Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn jẹ́ ìjọba Nàìjíríà, àjo àgbáyé lógún púpọ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

103

Ìjọba orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tuntun pẹ̀lú  ètò àjọ àgbáyé ní orílẹ̀ -èdè, láti mú  ìlọwọ́sí bá  ẹ̀tọ̀ ọmọnìyàn ní orílẹ̀ -èdè náà.

Ninu ijiroro kan ti wọn filọlẹ ni Ilu Abuja ni ọjọ iṣẹgun, awọn ẹgbẹ mejeeji bẹrẹ  ijiroro lori bi wọn  ṣe le rii  pe aabo to daju wa fun ẹtọ, ati imuse awọn apejọ ati awọn ofin lori awọn ẹtọ ọmọniyan, eyiti Naijiria  fọwọsi.

Nigbati o n soro nibi ifilọlọ naa , aarẹ ajọ agbaye UN ni Naijiria, Edward Kallon, sọ pe aabo ẹtọ ọmọniyan jẹ ọkan pataki ti  ajọ agbaye UN  lọwọsi.

Kallon, ti o ṣe aṣoju fun Peter Hawkins, Aṣoju Orilẹ -ede ti UNICEF, sọ pe Naijiria, gẹgẹ bii ọpọlọpọ awọn orilẹ -ede miiran, dojuko ọpọlọpọ awọn italaya ẹtọ ọmọniyan ti wọn ni lati yanju.

O salaye pe ijumọsọrọ pẹlu ijọba, yoo ṣe iranlọwọ lori  awọn akitiyan UN fun ilosiwaju  ẹtọ ọmọniyan.

Kallon tọka si pe,lati ṣaṣeyọri ,wọn gbọdọ dojukọ didasilẹ eto ilana kan ti yoo maa  ṣepade lorekore lati ṣe apapọ ayẹwo ifọwọsowọpọ  lori awọn ọrọ to ba jẹyọ lori ẹtọ ọmọniyan ni Naijiria.

Leave A Reply

Your email address will not be published.