Take a fresh look at your lifestyle.

Olùdíje Ẹgbẹ́ Òṣèlú APGA Arábìnrin Gwacham Jáwé Olúborí Nínú Ìbò Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Agbègbè Oyi/Ayamelum ní Ìpínlẹ̀ Anambra

0 270

Olùdíje Ẹgbẹ́ Òṣèlú All Progressive Grand Alliance (APGA) Arábìnrin Maureen Chinwe GWACHAM jáwé olúborí nínú ìbò Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí tán ní ìjọba àpapọ̀ ẹkùn Oyi/Ayamelum.

Gwacham jáwé olúborí pẹ̀lú ìbò 15,299 tí àwọn alátakò rẹ̀, Hon.Charles Uchenna Okafor (Wiper) ti ẹgbẹ́ òṣèlú Young Progressive Party(YPP) ni ibo 13,332, Chira Obiora Uzochukwu ti ẹgbẹ́ oṣelu Labour Party ni ìbò 8,159, àti ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìgbìmọ̀ asojú sòfin tẹ́lẹ̀ rí Hon. Vincent Ofumelu ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP náà ní ìbò 6,912, wọ́n sì kéde Arábìnrin Maureen Chinwe Gwacham gẹ́gẹ́ bí Olùborí.

Nígbà tí ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹkùn rẹ̀ tó fún ní ànfàní àti sìn ìlú nípa fífi ìbò gbée wọlé, ó rọ àwọn olùkópa yókù láti bá òun fọwọ́sowọ́pọ̀ láti jẹ́ kí ekùn náà tẹ̀síwájú.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button