Ẹgbẹ òṣèlú APC ló jáwé olubori ní àwọn ẹkùn ìdìbò Mẹ́tẹ̀ẹta tó wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gẹ́gẹ́ bí o ti farahàn nínú èsì ìdìbò tó wáyé ni ọjọ́ Karundinlọgbọn oṣù yìí.
Amòfin Sarafadeen Abiodun Alli ti o dije du ipò Aṣoju Ẹkùn Ìdìbò Gúsù Ọ̀yọ́ labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni àjọ eleto Ìdìbò, INEC ti kéde pé o jáwé olubori nínú ìdìbò náà.

Nígbàtí Sarafadeen Alli tí ẹgbẹ òṣèlú APC ní ibo 111,513, alatako rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP Olasunkanmi Tegbe ni ibo 92,481, tí Kolapo Koka-Daisi ẹgbẹ òṣèlú ‘Accord’ ni ibo 33,641, tí Oladimeji Theophilus ẹgbẹ òṣèlú LP náà si ni ibo 22,657.
Nígbà tí o kéde èsì ìdìbò náà ní ilé ẹkọ Gírámà Ikolaba ní Ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹni tí o ṣe akojọpọ èsì ìdìbò fún Ẹkun ìdìbò Gúsù Ọ̀yọ́, Ọjọgbọn Wole Olatokun ti ilé ẹkọ gíga Fafiti Ìbàdàn sàlàyé wí pé Sarafadeen Alli tí yege pẹ̀lú èsì ìdìbò náà ní ìbámu pẹlu òfin, tí o sì kéde rẹ gẹgẹ bíi olubori.
Bákan náà, ní ẹkùn ìdìbò Ààrin Gbùngbùn Ọ̀yọ́, Ọmọwe Yunus Akíntúndé ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló jáwé olubori pẹ̀lú ibo 108,776, nígbà tí alatako rẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Olóyè Bisi Ilaka ní ibo 101,213; ti Faozey Oladotun Nurudeen tí ẹgbẹ́ òṣèlú Accord náà si ní ibo 41,743.
Ọjọgbọn Adeniyi Olatubosun tíì ṣe Ọgá àgbà ilé ẹkọ Fasiti Kola Daisi lo se akojọpọ èsì ìbò Ààrin Gbùngbùn Ọ̀yọ́, tó sì kéde Ọmọwe Yunus Akíntúndé gẹgẹ bíi Olubori lati soju Ẹkùn Ìdìbò náà ni ilé ìgbìmò Aṣofin Àgbà.

Àwọn oludije mẹ́tẹ̀ta ni ẹkùn ìdìbò Ààrin Gbùngbùn Ọ̀yọ́, Ọmọwe Yunus Akíntúndé ti ẹgbẹ òṣèlú APC, Olóyè Bisi Ilaka ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àti Faozey Nurudeen lati inu ẹgbẹ òṣèlú Accord ni iwadii fi ìdí rẹ mulẹ wí pé o jẹ ọmọ bíbí ìlú Ọ̀yọ́.
Bẹẹni èsì ìdìbò Ẹkùn ìdìbò Àríwá Ọ̀yọ́ fi hàn wí pé Abdulfatai Buhari ti o sójú ẹkùn ìdìbò náà fún sáà méjì tí o sì tún n sojú ẹkùn ìdìbò náà lọwọ ló tun jáwé olubori nínú ètò ìdìbò Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣojú-Ṣofin to wáyé ni ọjọ́ Karundinlọgbọn oṣù yìí.

Awọn ti o figagbágà pẹ̀lú rẹ̀ ni Akinwale Akinwole ti ẹgbẹ òṣèlú PDP ati Shina Peller ẹgbẹ òṣèlú Accord.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply