Àjọ INEC gbóríyìn fún àwọn olùdìbò àti alẹ́nulọ́rọ̀ yòókù ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì fún àṣeyọrí ètò ìdìbò ọdún 2023
Alákóso àgbà fún Àjọ INEC ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀bámi Sàlámì ló gbóṣùbà o-káre yìí fún àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Èkìtì nígbá tí wọ́n parí ètò kika ìbò Ààrẹ tán ní Ilé-iṣẹ́ Àjọ INEC tó wà ní ìlú Àdó-Èkìtì, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Èkìtì.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Sàlámì sọ pé ìfowópamọ́ àwọn òǹdìbò àti àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ yòókù kó ipa pàtàkì nínú aṣéyọri ètò ìdìbò gbogboogbò náà
Alákóso àgbà Àjọ INEC náà fi múlẹ̀ pé àwọn Ikọ̀ Alákíyèsí tó ṣiṣẹ́ káàkiri Ìpínlẹ̀ Èkìtì jábọ̀ pé ètò ìdìbò náà wáyé ní irọwọ irọsẹ, tí àwọn òǹdìbò gba àlàáfíà láàyè. Ó ní:
“Àwọn Alákíyèsí, inú wọ́n dún pé, àwọn ara Ìpínlẹ̀ Ekiti fààyè gba àlàáfíà, wí pé omi àlàáfíà lomi tí à ń mu ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì.”
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rọ tuntun ‘Bimodal Voter Accreditation System’, ó ní ipa kékeré kọ́ ni ẹ̀rọ yìí kó nínú àṣeyọrí ètò ìdìbò yìí pàápàá fún àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ nínú ètò ìdìbò náà. Ó ní:
“BVAS’ tí a lò, inú gbogbo ènìyàn ló dùn sí i, àwọn ‘observers’ wa, inú wọ́n dún sì i, àwọn òǹdìbò, inú wọn dùn, àwa tá a mójú tó ìdìbò, inú wa dùn, torí pé, ó fọkàn wa balẹ̀.”
Ètò ìdìbò gbogboogbò ọdún 2023 ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì wáyé ní irọwọ irọsẹ, eléyìí tí wọ́n ka èsì ìbò náà, tí Olùdarí Ètò ìdìbò ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọláwálé Làsísì kéde rẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìkàbò náà. Èyí tí yóò jẹ Ìpínlẹ̀ àkọ́kọ́ tí Àjọ INEC yóò gbé èsì ètò ìdìbò wọn jáde nínú ètò ìdìbò gbogboogbò ọdún 2023
Lanre Lagada-Abayomi
Leave a Reply