Egbe Òṣèlú APC ti yege ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Opobo/Nkoro, Ìpínlẹ̀ Rivers nínú ìbò ààrẹ tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta tó kọjá. Ó jẹ́ agbègbè ibi ti Olùdíje Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP, Siminialaye Fubara ti wá.
Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC borí pẹ̀lú ìbò 5701 , Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP ni ìbò 1542, Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party se ipò Kejì pẹ̀lú ìbò 2093.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Paul Chukwuogwo ló kéde èsì ìbò náà níbi tí wọ́n ti ń se àkójọpọ̀ èsì ìbò ní gbọ̀ngan olú ìlú àjọ INEC ní Ìlú Port Harcourt.
Ìjọba ìbílẹ̀ tó kù tí wọ́n kéde ni Ahoada West, Tai àti Gokana.
Èsì ìbò gúsù Ahoada bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Cheta Williams, se kéde nìyí:
APC ní 3443 ìbò
PDP ní 2582 ibo
LP ní 4634 ìbò
SDP ní 147 ìbò
Olùkéde Ìbò fún ìjọba Ìbílẹ̀ Tai, Ọ̀jọ̀gbọ́n Williams Chinedu kéde bayi:
APC ní 9442 ìbò
PDP ní 1506 ibo
LP ní 485 ìbò
SDP ní 128 ìbò
Ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Gokana ni wọn kọ̀ látàrí àìṣedédé, ó sì ṣeéṣe kí wọ́n gbàá yẹ̀wò.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Yiiyitk Omaavadu fnk.mwli.yoruba.von.gov.ng.est.ee http://slkjfdf.net/