Mi ò ní yí padà kúrò lórí ìlànà bí wọ́n ṣe ń jẹ olúbàdàn -Ṣèyí Mákindé
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé ṣe àbẹ̀wò ẹkú araá-fẹ́ra kù sí opó Ọba Sálíù Adétúnjí, Ajéogungun I, Olúbádàn ti ìlú Ìbàdàn tí ó sì fi àsìkò ọ̀hún sèlérí pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò ṣe ayẹyẹ ìsìnkú ọlọ́lá fún ọba náà tó wàjà ní ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rùún.
Gomina Makinde, lasiko ti o se abẹwo si opo ati ẹbi Olubadan ọhun ni Aafin rẹ to wa ni Popo Yemoja ni ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ni ẹkun gusu iwọ oorun orile ede Naijiria tun fi asiko ọhun tẹnu mọ pe o ṣe pataki ki ilẹ Ibadan pada sori ilana bi wọn se n je ‘Olubadan’ latẹyinwa.
O wa sọ ninu ọrọ rẹ pe oun fi da gbogbo ọmọ bibi ilẹ ibadan loju pe, gẹgẹ bi ijọba oun koni ya kuro lori Ilana ati eto bi wọn se n j’oba nilu Ibadan. O wa fi kun pe, gbogbo ẹni ti o ba mọ pe oun ni’fẹ lati je OLUBADAN ni lati setan lati tele ilana to wa nilẹ.
Nigbati o n feesi, Raheem Adetunji ti i se omo olubada to pa’poda ohun fi emi imore han si abewo gomina si idile re ti o si gba ladura pe ki Olorun je ki gomina se aseyori ninu gbogbo idawole re pata.
Saaju abewo gomina si idile olubadan to waja ni igbimo afọbajẹ ti ṣe ipade lati le fẹnu ko lati yan ẹni ti yoo jẹ olubadan miran. Ipade ọhun lo waye ni Aafin to wa ni Ọja’ba nilu Ibadan sugbỌn ti won ko ba awon akọroyin so ohunkohun to jẹyọ ninu ipade ọhun.
Lẹyin iyalode Ilẹ Ibadan ( Oloye Theresa Oladuntan Oyekanmi) ẹni ti ko farahan nibi ipade latari ailera rẹ, ati Osi-Olubadan Ilẹ Ibadan (Agba-Oye Adewolu Ladoja), awon ti o peju sibi ipade ohun ni :Asipa Olubadan to ile Ibadan(Agba Oye Eddy Oyewole); Ekerin Olubadan, Agba Oye Abiodun Kola Daisi; Balogun Olubadan (Agba Oye Owolabi Olakulehin; Otun Balogun (Agba Oye Tajudeen Abiola; ati Osi Balogun (Agba Oye Lateef Gbadamosi Adebimpe).
Awọn yooku to wa nibi ipade ọhun ni: Asipa Balogun (Agba Oye Kola Adegbola); Ekerin Balogun (Agba Oye Olubunmi Osioye). Bakan naa ni a ri asoju ijọba ipinlẹ Ọyọ, abilekọ Grace Arẹmu, ti i se Alakoso (HLA) ijọba ibilẹ gusu ila-oorun Ibadan nibi ti ipade ọhun ti waye.
Abiọla Ọlọwẹ
Ilu Ibadan.
Leave a Reply