Take a fresh look at your lifestyle.

Ètò Ìpèsè oúnjẹ fún Ilé-ìwé Ṣe àlékún Ìforúkọsílẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ jákèjádò Nàìjíríà – UN

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 342

Àjọ Àgbáyé tó ń rísí Ètò Oúnje  (WFP) sọ pé Ètò fífún Ilé-ìwé l’óúnjẹ ọ̀gbìn Orílẹ̀-èdè (NHGSFP) ti jẹ́ kí àwọn tó ń kàwé pọ̀ si jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Gẹgẹ bi Eto Ounjẹ Agbaye 2021, agbekalẹ naa ti pese  ounjẹ jijẹ fun awọn ọmọ ile-iwe to ju miliọnu mẹsan ni awọn ile-iwe alakọbẹrẹ ẹgbẹrun mẹtale-laadọta, eyiti o jẹ ki o jẹ ọkan ninu awọn eto ifun ile-iwe l’ounjẹ ti o tobi julọ ni Afirika.

Bi awọn ile-iwe ti tun wọle jakejado orilẹ-ede , Ile-iṣẹ to n mojuto Awọn ọran ọmọniyan, Isakoso Ajalu ati Idagbasoke Awujọ lapapọ (FMHADMSD) pẹlu atilẹyin imọ-ẹrọ lati Eto Ounjẹ Agbaye ti kede pe yoo tun mu Eto ifun Ile-iwe l’ounjẹ  Orilẹ-ede bọ si ipele miran.

Awọn abajade ipinnu yii wa lati inu igbelewọn apapọ ti wọn ṣe ni idasi mẹrin ọdun 2021, lati le mọ  awọn ọna  ilọsiwaju, idagbasoke ati imuduro NHGSFP.

Minisita fun ọrọ ọmọniyan, Isakoso Ajalu ati Idagbasoke Awujọ Sadiya Farouq, sọ pe eto naa tun jẹ  idasi pataki ninu iṣakoso  aarẹ Muhammadu Buhari.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button