Àyíká Àìléwu: Àjo Ààbò Àgbáyé fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Àgùnbánirọ̀, NYSC
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àjọ Ààbò Àgbáyé, (WSO) ti fọwọ́ sí ìwé àdéhùn tí ó yẹ pẹ̀lú Àgùnbánirọ̀, NYSC, láti ṣe ìtanijí lórí ìhùwàsí ìgbé ayé àìléwu àti àyíká fún gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Aarẹ ajọ ọhun, Ọgbẹni Soji Olalokun, nigba ti o n buwọlu iwe-adehun ọhun ni olu ile-iṣẹ NYSC ni Abuja, sọ pe ajọṣepọ naa yoo pese anfaani lori ilera, ailewu, aabo, ayika, igbaradi fun pajawiri ati idahun, imọ-ẹrọ idena ijamba, ati awọn miiran fun awọn agunbanirọ oluyọọda.
Gẹgẹ bi Olalokun ti sọ,wọn ṣe imurasilẹ idahun pajawiri si aabo yii fun igbaradi awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati ṣẹda iwa gbigbe ati agbegbe ni ibi iṣẹ, awọn ile-iwe ati ni gbogbo oju gbangba.
Leave a Reply