Take a fresh look at your lifestyle.

Manchester City Gbá Omijé Lójú Inter Milan Látí Gbá Ìfé UEFA Champions League

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 323

Ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù Manchester City parí sáà ìgbábọ́ọ̀lù 2022/2023 ní ọnà àrà bó ṣé f’ojú Inter Milan gbọ́lẹ̀ nínú ìdíje tí UEFA Champions League pẹ̀lú àmì ayò 1-0 fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn wọ́n, ní pápá ìṣere Ataturk Olympic Stadium ní Istanbul, Turkey.

Ìkọ Gẹ̀ẹ́sì náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Erling Haaland ní iwájú, pẹ̀lú Bernado Silva àtí Jack Grealish lẹ́gbẹ́ ọtún àti òsì rẹ̀. Fún Inter, ẹgbẹ́ Italy ṣé àfihàn Edin Dzeko àti Lautaro Martinez nínú ìkọ rẹ̀ lọ́wọ́ iwájú látí jẹ́ kí ìfẹ́sẹ́wọ́nsẹ́ náà gbóná jọin-jọin.

Ní ìdá àkọ́kọ́, Man City jẹ́ gábá lórí ìfẹ́sẹ́wọ́nsẹ́ ṣùgbọ́n wọ́n kò lé yẹ́lé Inter wò. Àgbábọ́ọ̀lù àárín fún City, Kevin de Bruyne ní ifarapa tí wọ́n sì rọ́pò rẹ̀ ní ìṣẹ́ju kẹrindinlogoji 36th pẹ̀lú Phil Foden. Àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì gbá ọ̀mì 0-0 ní ìdá àkọ́kọ́.

Ní ìdá Kejì, àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì jáde pẹ̀lú àkitiyan látí bórí ìdíje náà. Ìkọ Manchester City sí gbá àmì ayò wọlé ní ìṣẹ́jú kejìdínlàádọrin 68th lati ẹ̀sẹ̀ àgbábọ́ọ̀lù nípò àárín ọmọ Orílẹ̀-èdè Spain, Rodri.

Inter náà gbìyànjú ọnà àbáyọ́ ṣùgbọ́n wọ́n kò lé kọjá lára goli Manchester City títí tí ìfẹ́sẹ́wọ́nsẹ́ náà fí wá sí òpin.

Man City ló tí gbà ìfé English Premiership,FA Cup àtí pàápàá jùlọ UEFA Champions League ní ìparí sáà 2022/2023 irúfẹ́ rẹ̀ tí àwọn àkẹgbẹ́ wọ́n Manchester United náà ṣé ní sáà 1998/1999.

Olùkọ́ní Manchester City Pep Guardiola tí gbá ìfé ẹ̀yẹ Champions League ní ìgbà mẹ́ta bayii, èyí tó mú gbogbo ìfé tó gbà fún ìkọ Man City dí Méjìlá.

Tún kà nípa:Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Manchester United Fẹ́ Fún Ògbóǹtarìgì Agbábọ́ọ̀lù, Kane Ní £300,000 Ní Ọ̀sẹ̀ Kọ̀ọ̀kan

Guardiola tún dì Olùkọ́ní àkọ́kọ́ látí ṣaṣeyọri irúfẹ́ ìfé mẹta báyìí nílẹ́ Yúrópù, lẹyìn tó tí gbàá bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìkọ Barcelona tí Orílẹ̀-èdè Spain ní ọdún 2009.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button