Take a fresh look at your lifestyle.

Òkòwò Iṣẹ Àgbẹ̀: Makinde Ṣe Àbẹ̀wò Sí Ilégbèé Oko Fáṣọlá, Ilé iṣẹ Ṣuga Àti Òpópónà Iseyin Sí Ogbomoso.

0 243

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ṣe àbẹwò sí ilégbèé Oko Fáṣọlá, Ilé iṣẹ́ Ṣuga àti Òpópónà Iseyin-Ogbomoso-Fapote lati mọ ibi tí ọwọ iṣẹ́ dé dúró, tí o sì sàlàyé pé àwọn ilé iṣẹ wọnyii yóò mú adinku dé bá bí àwọn èèyàn ṣe n fi ìgbèríko silẹ lọ sí ìgboro.

Nígbà tí o n ba àwọn oníròyìn sọrọ lẹyin to rin tìbú-tòòró ilégbèé Ẹlẹgbẹrun Méjìlá Sarè (1200 Hectares) Oko Fáṣọlá náà, to wáyé ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Iwọ Oòrùn Ọ̀yọ́, tó sì fí idunnu rẹ hàn sí ibi ti wọn bá iṣẹ náà dé. O sàlàyé pé àwọn èèyàn agbègbè náà yóò bẹrẹ sí mọ rírì iṣẹ́ ti Ìjọba n ṣe.
O wa rọ àwọn èèyàn náà láti fi ọwọ́ so’wọpọ pẹlu ìjọba.

Bákan náà, Gómìnà tún fi yé wọn pé, ìjọba ṣe àgbékalẹ̀ okòwò yìí nipasẹ ajọṣepọ Ìjọba àti Aládàáni (Private Public Partnership), nígbà tí o fi dá wọn lójú pé ìṣèjọba òun yóò tubọ máa pèsè àyíká to rọrùn fún okòwò láti gbèrú síi.

Gómìnà wá ṣe afọmọ àlàyé rẹ nígbà tó tẹnu mọ pé, ni kété ti ilé iṣé Ṣuga àti Ilégbèé Oko Fáṣọlá yìí bá tí parí, adinku yóò dé bá iye àwọn èèyàn tó n fí ìgbèríko silẹ lọ sí ìgboro latari àìrí iṣé.

Gómìnà wá fi àsìkò náà mẹnu ba àwọn iṣẹ àkànṣe tí o n lọ bíi: Ahéré Oko; Ilégbèé fún àwọn Àgbẹ̀; Ààyè ti wọn ti n tún ohun èlò iṣé ṣe; Ilé iṣé to n pèsè Wàrà àti Ọna tó dára

Gómìnà tún sàlàyé pe àwọn agbẹ to jẹ ọdọ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti wọn ti gba idanilẹkọ ní Ìpínlẹ̀ Nassarawa eléyìí tí ìṣèjọba Makinde ṣe agbatẹru rẹ̀ labẹ ẹ̀ka tó n ṣe ironilagbara fún àwọn ọdọ lórí òkòwò iṣẹ Agbẹ ‘Youth Entrepreneurship Agribusiness Program’s(YEAR) náà wà níbè.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button