Take a fresh look at your lifestyle.

Eré Kiriketi: Nàìjíríà Bórí Rwanda Nínú Ìdíje Kwibuka T20

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 253

Ẹgbẹ́ àgbà eré cricket tí àwọn Obìnrin tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, “female Yellow Greens” ní ọjọ́ àbámẹ́ta bórí Rwanda pẹ̀lú àwọn wickets mẹfa nínú ìfẹ́sẹ́wọ́nsẹ́ àkọ́kọ́ wọ́n tí ìdíje “9th Kwibuka T20 Women’s tournament,” ní pápá ìṣere Gahanga Cricket Stadium ni Kigali, Rwanda.

Gisele Ishimwe gbìyànjú gidigidi fún ìkọ rẹ̀ pẹ̀lú 30runs nínú 39balls ṣùgbọ́n ìkọ Nàìjíríà náà ṣé àkitiyan látí ṣé ìdíwọ́ fún wọn.

Adeshola Adekunle tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Oyesande Omonkhobhio ṣé gbá wickets méjì àtí ọkàn, lẹsẹsẹ, bí wọ́n ṣé ṣé ìrànlọ́wọ́ láti fí òpin sí Rwanda 87/7 nínú 20 overs.

Èyí ló fún ìkọ Nàìjíríà ní anfààní látí gbá 88 nínú 18.2 over.

Nàìjíríà yóò kojú Botswana ní òwúrọ̀ àti Kenya ní ọsán ọjọ́ Àìkú. Uganda tún ní ègbé mìíràn tí wọ́n yóò kojú nínú ìdíje tí â n’ìrètí pé yóò parí ní ọjọ́ Ẹtì.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button