Take a fresh look at your lifestyle.

Kó Sí Ìgbàlààyé Fún Onijagidijagan Kọ̀ọ̀kan Ní Lake Chad Island – Olùdarí MNJTF

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 342

Ẹgbẹ́ àkójọpọ̀ àwọn Orílẹ̀-èdè MNJTF sọ pé àwọn tí pinnu láti má gbá áwọn Onijagidijagan láyé lórí èyíkéyìí ilẹ̀ Lake Chad

Olùdarí ẹgbẹ́ àwọn Orílẹ̀-èdè náà MNJTF, Major General Gold Chibuisi ṣé àlàyé náà làkókò àbẹ̀wò iṣẹ́ kàn sí Blangoua ní Orílẹ̀-èdè Cameron, Bagasola àtí Bibi ní Orílẹ̀-èdè Chad Republic.

Èyí wá lẹyìn irú àbẹ̀wò kàn sí Malam-Fatori ní Nigeria, Diffa àtí Bosso ní Niger Republic èyítí o ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àkitiyan tí nlọ lọ́wọ́ látí bórí àwọn Onijagidijagan àtí àwọn ọlọtẹ ní Lake Chad.


Tún kà nípa:Ẹgbẹ́ Ọmọ Ológun MNJTF Kan Àwọn Oníṣe Láabi Lábùkù, Àwọn Mẹ́jọ Tú Bá.

Ó rọ̀ àwọn ọmọ ogún látí dúró ṣinṣin nínú àtìlẹ́yìn wọ́n.

Láti tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ Operation Lake Sanity ní àdínkù tí bá àgbàrá àwọn Boko Haram ní pàtàkì láti gbèrò tàbí ṣiṣẹ́ ní àwọn erékùṣù Lake Chad tí a mọ̀ sí “Tumbus”.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button