Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara ṣíṣọ lójú ọjà káríayé Gbùgbù

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 441

Àwọn ènìyàn agbègbè Gbùgbù ti gbóríyìn fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara , AbdulRahman AbdulRazaq, lórí ṣíṣí ipele àkọ́kọ́ ọjà káríayé Gbùgbù.

Emir ti Lafiagi, Alhaji Muhammed Kudu Kawu,ṣàpèjúwe ìdàgbàsókè náà gẹ́gẹ́ bí oríire, tí ó sì sọ pé,ó yẹ kí wọ́n fún gómìnà AbdulRazaq ní àǹfàní ọdún mẹ́rin si fún àwọn ǹkan mèremère tó ti ṣe àti àánú tó ní fún àwọn ènìyàn,pàápàá jùlọ àwọn ènìyàn ìgberíko.

 

Emir náà sọ pé gbogbo àwọn táwọn ń gbé lágbègbè náà ni yóò mọ rírì ǹkan tí gómìnà ṣe fún wọn.

Ó wá dúpẹ́ lọ́wọ́ ìṣàkóso náà fún ìgbìyànjú rẹ̀ lórí àtúnṣe ibùdó ìtajà náà.

Àwọn tí ó tún pẹ̀lu gómìnà ní ṣíṣí ọjà náà ni Sẹ́nétọ̀ Sadiq Umar; ọmọ ẹgbé ilé-Aṣòju ṣòfin; àwọn ìgbìmọ̀ asòfin ní ìpínlẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba,pẹ̀lu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ń ṣòkóso ìjọ́ba.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button