Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ́ Tiwá-lẹ́yìn Fún Ètò Ìlera Tó Múná Dóko – Kọmisana Anambra

0 565

Kọmisana fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Anambra, Dókítà Afam Obidike tí ke sí gbogbo aráàlú látí ṣé àtìlẹ́yìn fún ìjọba ìpínlẹ̀ náà látí ṣé àṣeyọrí lórí ètò ìlera tó múná dóko pẹ̀lú owó kékeré fún gbogbo ènìyàn.

Dókítà Obidike bẹ̀bẹ̀ èyí làkókò tó ń ṣé ìfilọ́lẹ̀ Ilé-Ìwòsàn Saint Michael, Onono, Umuikwu Anam, Ìjọba Ìbílẹ̀ Ìwọ̀-oòrùn, ìpínlẹ̀ Anambra.

Kọmisọna sọ èyí dì mímọ̀ pé Gómìnà Chukwuma Soludo ń ṣé òun gbogbo látí ríi dájú pé àwọn tó ngbé ní àwọn ìgbèríko ní ẹtọ sí ètò ìlera tó dára, àtí pé ibasepọ ìjọba àtí aráàlú Public Private Community Partnership PPCP, èyí tí Gómìnà gbé kalẹ̀ ní ọnà tó dára jùlọ látí ṣé àṣeyọrí ètò ìlera tó múná dóko ní ìpínlẹ̀ náà.

Tún kà nípa: Mo fẹ́ Kí Ìbáṣepọ̀ Tó Dàn Mọ́rán Wa Láàrín Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìjọba Àti Àwọn Adájọ́: Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra.

Dókítà Obidike tó bú ìyìn fún Olóyè Osita Offorzor tó kọ̀ ilé ìwòsàn náà fún ìrànwọ́ omo ènìyàn, ó wá rọ̀ gbogbo àwọn olùgbé àtí ẹgbẹ́ tó lówó Káàkiri Ìpínlẹ̀ náà látí farawe Olóyè yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìjọba yóò ṣé òun gbogbo tí ènìyàn bá ṣé látí mú kí ilé ìwòsàn náà di nlá.

Olóore náà, Oloye Offorzor sọ pé òun kọ Ilé-Ìwòsàn náà láti fopin sí ikú ainidi nítorí aini Ilé-Ìwòsàn ní àgbègbè rẹ̀, o sí rawọ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra látí rán àwọn òṣìṣẹ́ ìlera tó péye láti ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ náà.

Ọmọ ẹgbẹ́ tó ń ṣójú Anambra West nile ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà, Oloye Patrick Obalum-Udoba, Olóyè Michael Okafor-Nwofia láàrín àwọn mìíràn ló wà níbí ayẹyẹ náà.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button