Ìgbìmọ̀ ẹ̀sọ́ òpópónà fún àwọn òṣìṣé tó gbéga lámì ìyẹ́sí ní ìpínlẹ̀ Anambra
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìgbìmọ̀ tó ń rírí ààbò òpópónà (FRSC), ti agbègbè ìpínlẹ̀ Anambra , ti fi àmì ìyẹ́sí dá àwọn òṣìṣẹ́ márùnlé-lógógì nínú àwọn méjìlé-láàdọ́rin tí ó gba ìgbéga sí ipò tuntun,ní ọjọ́ Ìṣégun.
Ọ̀gbẹ́ni Adéoyè Irelewuyi, adarí ikọ̀ náà, sọ pé èyí jẹ́ àkọ́kọ́ rẹ̀ nínú ìtàn agbègbè náà, láti ní àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n fún ní ìgbéga tí ó pọ̀ tó yẹn,lásìkò ayẹyẹ náà.
Irelewuyi wá rọ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n gba ìgbéga sí ipò tuntun láti mọ̀ pé, ìgbéga náà jẹ́ sí ti ojúṣe tó tún ga síi ,ìdánwò ìdarí àti agbára ìṣàkóso láti ṣàṣeyọrí lórí ìpinnu ìlànà ọgbọ́n ọdún 2023.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Kọmísọ́nà fún àwọn Agbófinró ní Anambra, Echeng Echeng, tí Peter Ozigi, igbákejì Kọmísọ́nà fún àwọn Agbófinró sojú,wá rọ àwọn òsìṣẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéga láti kún fún àdúrà,kí wọ́n fọkàn sí ǹkan tí wọ́n ń ṣe,kí wọ́n sì fi ojú ṣórí.
Leave a Reply