Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Enugu tẹ́lẹ̀ rí buwọ́lu àtúnyàn Ààrẹ Tinubu

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

198

 Gómìnà ìpínlẹ̀ Enugu nígbà kan rí, Ọ̀gbẹ́ni Sullivan Chime, ti buwọ́lu ìpinnu àwọn gómìnà Gúsù ilá oòrùn, àwọn adarí àti àwọn tó nííṣe ti ẹgbẹ́ All Progressives Congress ní Ẹkùn náà, láti ṣàtìlẹyìn fún àtúnyàn Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fún ìgbà kejì, tí ó sì sọ pé ààrẹ ti ṣe àwọn iṣé tó jọjú.

Chime, to kede pe oun ti wa lara awọn ti wọn buwọluu lati ibẹrẹ sọ pe, oun ko ṣẹ iye meji pe Tinubu ati APC yoo gbegba oroke nibi ibo Gusu iwọ oorun ti n bọ ni 2027.

Gomina tẹlẹ yii sọrọ ni Udi, lasiko ti wọn n ṣeayẹyẹ ifilọlẹ iforukọsilẹ APC lori ayelujara ni ijọba agbegbe iwọ oorun ni ọjọ Iṣẹgun, wipe yoo to ye awọn ti wọn kọti ikun ni Ẹkun naa ti oju wọn yoo si la.

Gomina tẹlẹ naa ni oun yoo tunbọ sọrọ siwaju ni awọn oṣu ti bọ ni 2027.

Ti o si n fi idunnu rẹ han bi Gusu iwọ oorun, ipinlẹ Enugu paapaa julọ, ṣe n ṣatẹwọgba APC, o wa sọ pe oun ṣẹṣẹ wa mọ riri bi oun ṣe fi ẹgbẹ Peoples Democratic (PDP) silẹ, lẹyin idibo 2015.

Olugbalejo, Alaga ati Alaga ijọba agbegbe Udi, Ọloye Hyginus Agu; Alaga ti ijọba ibilẹ Aninri , Ọmọ ọba Ugochukwu Nwanjoku; Alaga ibilẹ Awgu , Oloye Uchenna Okoko; Alaga ijọba ibilẹ Ezeagu , Dokita Vita Ndu; ati Alaga ijọba ibilẹ Oji , Aṣoju Greg Anyaegbudike, sọ ninu ọrọ wọn pe awọn ṣetan lati korajọ lọ si igberiko ati lati adugbo si adugbo fun iforukọ silẹ awọn ọmọ ẹgbẹ to ju miliọnu meji lọ.

Comments are closed.

button