Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu gbóríyìn fún olóyè Bisi Akande ní ọdún mẹ́tàdín- láàdọ́rún

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

79

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti gbé òṣùbà ràbàtà fún àgbà ìlú tí ó tún fìgbà kan jẹ́ Alága Àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), Olóyè Bisi Akande, bí ó ṣe ṣe àjọ̀dún ọdún mẹ́tàdín- láàdọ́rún ọjọ́bìí rẹ̀.

Ninu atẹjade pataki kan to jade ni ọjọ Ẹti, Ààrẹ ṣajọyọ iṣẹ takuntakun ati ifọkansin ijọba tiwantiwa pẹlu oloye Akande.

O ṣapejuwe oloye Akande bi ogbontarigi oloṣelu ti o ko ipa pataki ni ṣiṣatunṣe lori idagbasoke oṣelu Naijiria ati ifidimulẹ awọn ẹka ijọba tiwantiwa.

Oloye Bisi Akande bẹrẹ iṣẹ bii oluṣe iṣiro pẹlu ile iṣẹ Elepo ilẹ ti British ki to kuro ni ẹka aladani lọ si ti ijọba.

O fi igba kan jẹ Akọwe fun ile ijọba ti ipinlẹ Ọyọ ti tẹlẹ ni ọdun 1979 ti si di igbakeji Gomina lasioko iṣejọba elẹekeji.

Aarẹ Tinubu sọ pe, “Akande tun wa ṣe Gomina Ọṣun lati 1999 si 2003, ti o si tun ṣe gudugudu meje yaayaa mẹfa.

Gẹgẹ bi Alaga fidihẹ ẹgbẹ APC, Akande ṣe ipilẹ itan aṣeyege fun ẹgbẹ naa ni 2015,” Tinubu sọ bayii.

O tun wa sọ pe, koda ni ọdun kẹtadin-laadọrun, Akande ṣi tun jẹ aloporo ijọba tiwantiwa, iṣe deede laarin ara ilu ati iṣejọba to dara.

Aarẹ wa gbadura alaafia fun Akande ati ọtun ilera bi o ṣẹ n ṣayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

Comments are closed.

button