Àjọ Àgbáyé ti fi àníyàn hàn lórí bí wọn ṣe ni fi òfin dè awọn oloṣèlú ní Burkina Faso, lẹ́yìn àwọn ìgbésẹ̀ tuntun tí ìjọba ológun ṣe láti fa àkókò iṣejọba rẹ̀ gùn àti láti fòfin de àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú.
Ní nǹkan bí ọdún mẹ́rin lẹ́yìn tí ó ti gba agbára, olórí Burkina Faso, Ibrahim Traoré, ti rọ àwọn aráàlú láti tún ronú nípa ìdúróṣinṣin wọn sí ìṣàkóso ìjọba tiwantiwa, èyí tí ó ń mú kí àríyànjiyàn pọ̀ sí i lórí ìtọ́sọ́nà oṣèlú orílẹ̀-èdè náà.
Nínú ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè kan láìpẹ́ yìí, Traoré ṣàpèjúwe ìjọba tiwantiwa gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó léwu sí àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà, ó ń jiyàn pé ó ti kùnà láti dáàbò bo àwọn aráàlú láààrin àìní ààbò. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá bí ìjọba rẹ̀ ṣe ń tẹ̀síwájú láti mú àṣẹ pọ̀ sí i lẹ́yìn ìgbà tí ológun gba ìjọba ní ọdún 2022 tí ó mú un dé orí aleefa.
Láti ìgbà tí ó ti di olórí, ìjọba ológun ti gbéra láti tú àwọn ilé-iṣẹ́ tiwantiwa pàtàkì ká. O ti tú ìgbìmọ̀ ìdìbò orílẹ̀-èdè náà ká, àti pé àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, tí o ti dá dúró tẹ́lẹ̀ lẹ́yìn ìdìbò, ni o ti fòfin dè níti òfin báyìí. Àwọn aláṣẹ tún ti fa ìyípadà sí ìjọba tiwantiwa gùn sí ọdún márùn-ún, èyí tí ó mu ìpinnu ìṣáájú máa fà bi ìgbín láti mú ìjọba tiwantiwa padà sípò ní àárín ọdún 2024
Orílẹ̀-èdè Burkina Faso ṣì wà nínú ìwa-ipa jihadist tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́wàá tí ó ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀mí ènìyàn tí ó sì ti lé àwọn mílíọ̀nù ènìyàn kúrò ní ipò wọn. Ìjọba ológun sọ pé ìṣàkóso tó lágbára láti yanjú ìṣòro náà ṣe pàtàkì láti yanjú rẹ̀.
Ṣùgbọ́n, àwọn òṣìṣẹ́ Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, UN ti ké sí àwọn aláṣẹ láti mú àwọn ìdènà kúrò lórí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú kí wọ́n sì mú òmìnira àwọn aráàlú padà bọ̀ sípò, wọ́n kìlọ̀ pé ààyè oṣèlú tó ń dínkù tabi sofo lè tún ba ìdúróṣinṣin jẹ́ ní orílẹ̀-èdè náà.
Temitọ́pè Òbísẹ̀san