Take a fresh look at your lifestyle.

Póòpù Leo Rọ Herzog Ti Ísírẹ́lì Láti Fòpin Sí Ogun Iran

79

 

Póòpù Leo ní ọjọ́ Ẹtì bá Ààrẹ Ísírẹ́lì Isaac Herzog sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, ó sì rọ àwọn ènìyàn láti tún ìjíròrò ṣe láti mú kí ìjà Iran tó ń lọ lọ́wọ́ dópin, Vatican sọ èyí.

Póòpù ké sí olórí Ísírẹ́lì láti “tún gbogbo ipa ìjíròrò ṣe” gẹ́gẹ́ bí apá kan nínú ìsapá láti dín wàhálà kù kí ó sì mú ki àlàáfíà padà sí agbègbè náà.

Ó tún tẹnu mọ́ bi ọ se ṣe pataki láti dáàbò bo àwọn aráàlú àti láti bọ̀wọ̀ fún òfin àgbáyé àti ti ti awọn eniyan, èyí sì mú kí àníyàn Vatican nípa ipa ìlera ènìyàn ti ìjà náà ń ní lórí rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i.

Vatican sọ pé Póòpù ti ń sọ̀rọ̀ nípa ogun náà, ó sì ń pè fún ìpinnu àlàáfíà àti ìtẹ̀lé àwọn ìlànà òfin àgbáyé leralera.

 

Temitọ́pè Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button