Àjọ The Nigeria Governors’ Forum (NGF) ti kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ara Agwan Rukubati ipinlẹ Plateau nibi ti ọ̀gọ̀ èrò ti gbẹmi mi ti wọ́n sì sọ ọpọ eniyan di aláabọ̀ ara.
Èyí jẹyọ nínú gbólóhùn ààrẹ àjọ àwọn Gómìnà, AbdulRahman AbdulRazaq to tun jẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara tọ buwolù.
Àjọ NGF ranṣẹ ìbánikẹ́dùn sí àwọn ìdílé tí ọran náà kan ati ijọba ìpínlẹ̀ Plateau, wọn sì gboriyin fún Gómìnà Caleb Muftwang fún yiyara lọ sabewò síbi iṣẹlẹ naa lẹyin iṣẹlẹ, Ó wa gbàdúrà wipe ki Ọlọrun tẹ awọn òkú sì afẹfẹ rere ati pe àwọn ti wọn wa laaye ti wọn farapa kí ara wọn tètè yá
Temitọ́pè Òbísẹ̀san