Ilé-iṣẹ́ fún Ìṣàkóso àti Ìdènà Àrùn lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, (Nigeria Centre for Disease Control and Prevention NCDC), sọ pé àwọn àrùn Covid-19 Omicron tó ṣé òkùnfà púpọ sí àrùn yí ni àwọn orílẹ̀-èdè bí China, Amẹ́ríkà, àti United Kingdom, kò tíì dé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
NCDC sọ èyí dì mímọ ní ìmúdójúìwọ̀n lórí àyẹwò ẹdà àrà tí Covid-19 nípasẹ̀ Olùdarí Gbogbogbò rẹ̀, Dókítà Ifedayo Adetifa.
Ìmúdójúìwọ̀n náà fihàn pé àjàkálẹ̀ ààrùn COVID-19 Omicron tí ó ṣé òkùnfà púpọ sí rẹ̀ ni AMẸ́RÍKÀ àti UK jẹ́ XBB.1.5; nígbà tí BF.7 ṣé òkùnfà ọ̀pọ̀ rẹ̀ ní Ìlú China.
Adetifa, sọ pé, sibẹsibẹ, “B.5.2.1 ní a tí rí ní Nàìjíríà látí Oṣù Keje, ọdún tó kọjá.”
O sọ pé, àwọn yóò máa ṣé àyẹwò àwọn arinrin-ajo tó ń bọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fínífíní, pẹlú Ìbéèrè fún àwọn èsì ìdánwò PCR látí ọdọ àwọn aririn àjò tí ń wọlé, nítorí pé àkókó díẹ̀ ni àrùn COVID-19 Omicron náà ní látí tán kalẹ bí a tí rí káàkiri àgbáyé.
Adetifa ṣé ìlérí pé NCDC yóò tẹ̀síwájú látí ṣé abojuto àyẹwò àrà lórí àjàkálẹ̀ àrùn náà ní orílẹ̀-èdè yìí, àtí bí náà ṣé ń lọ́ káàkiri orílẹ̀-èdè. Ọ Sí rọ́ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí látí gbà àbẹ́rẹ́ àjẹsára látí dènà àrùn COVID-19 Omicron
Lekan Orenuga
Leave a Reply