Take a fresh look at your lifestyle.

Ajagunfẹ̀yìntì Abdulmalik, Olóníṣakin, Burutai ṣe àbẹ̀wò sí Ilé Aṣòfin Èkó

0 233

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa gba alejo Igbimọ Alaabo ati Ọgbọn Atinuda ninu ikọ amojuto eto ipolongo ibo Aarẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti wọn ṣe abẹwo si Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko lọjọ Iṣẹgun.

Abẹwo yii waye ni nnkan bi oṣu diẹ si asiko ti eto idibo gbogboogbo yoo waye ni lorilẹ-ede Naijiria, eleyii ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu jẹ ondije Aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC naa.

Igbimọ naa ti Ajagunfẹyinti Jubril Abdumalik ṣaaju, pẹlu awọn eniyan jankajankan miiran bii Ọgagun agba Abayọmi Oloniṣakin Olori ẹka eto aabo orilẹ-ede Naijiria, Ọgagun agba Tukur Buratai, Ọga-agba ile-iṣẹ ologun ilẹ. Ni kete ni wọn wọle fun ipade idakọnkọ.

Awọn miiran ti wọn kọwọ tẹle igbimọ naa rin ni Igbakeji Giwa Ọlọpaa tẹlẹri ni orilẹ-ede Naijiria, Ọgbẹni Hakeem Odumosu ati Dokita Abdurrazaq Balogun, ti o jẹ aṣofin tẹlẹ ni Ile Igbimọ Aṣofin naa, ti o jẹ Alakoso Igbimọ Ikowojọ fun Eto Aabo ni Ipinlẹ Eko ni bayii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button