Atiku Abubakar Ló Lè Mú Ìṣọ̀kan Dé Bá Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà – Alákóso Ìpolongo Ìdìbò Fún Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP
Alákóso ipolongo ìdìbò ní ẹkùn Gúsù Orilẹ Èdè Nàìjíríà fún Oludije du ipo Ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ òṣèlú PDP, Alhaji Atiku Abubakar ti sọ di mímọ pé iṣọkan àti ayípadà yóò dé bá ilẹ yìí tí ọmọ orilẹ èdè Nàìjíríà ba fi ibo wọn gbé Alhaji Atiku Abubakar wọlé gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ nínú ètò ìdìbò gbogboògbò to n bọ.
Ọgbeni Jide Ajani tí o ti fi igba kan ri jẹ ọgá FERMA lo fi idi ọrọ yi mu’le lásìkò tí àwọn ololufẹ ẹgbẹ òṣèlú PDP kowo rìn pẹlu àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ náà nínú “Ìrìn Òmìnira” ni iṣọkan pẹlu Aarẹ Atiku Abubakar ni ìlú ìbàdàn tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orilẹ èdè Nàìjíríà. Irin naa ni o bẹrẹ lati agbegbe Total Garden to sì parí sí gbọgán Mapo ni ìlú ìbàdàn.

Nigba tí o n sọrọ, Ajani mú dá gbogbo àwọn tó péjú wípé ẹya Yorùbá kò ní fi ika a abamọ há ẹnu ti wọ́n ba dibo fún Atiku gẹgẹ bíi Ààrẹ orilẹ èdè yìí nítorí Atiku kii se ẹlẹyamẹya. O wa tun fi da wọn lójú wípé, Atiku ti ṣèlérí láti mú àtúnṣe ati atunto dé bá gbogbo ẹka ìṣèjọba eléyìí tí o ti dénú ko’le, ni pataki jùlọ ètò ààbò emi ati dukia, tí yóò sì tún se agbekale ọlọpa agbègbè, ti gbogbo eya jakejado orilẹ èdè Nàìjíríà yóò sì lè jẹ mudun mudun ìjọba awa-ara-wa láì yọ ẹyà kankan silẹ.

Bákan náà ni igbákejì Alákóso ipolongo idibo, Olóyè Jumoke Akinjide náà ro gbogbo ọmọ ẹgbẹ òṣèlú PDP lati dibo wọn fún Atiku ati lati fi ibo wọn gbé Seyi Makinde wọlé lẹẹkan síi gẹgẹ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Lara awọn ti o darapọ mọ “Ìrìn Òmìnira” náà ni: Oloye Jumoke Akinjide tíì ṣe Mínísítà abele fún olú ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (FCT); Igbakeji gomina Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Bayo Lawal; Oludije du ipò gómìnà ni ipinlẹ Ogun, Ladi Adebutu ati àwọn eekan nínú ẹgbẹ òṣèlú PDP.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply