Take a fresh look at your lifestyle.

UK fún Àwọn dókítà Nàìjíríà mérìnlá- dín- lọ́rin-lé-nígba níwèé àṣẹ láàrin oṣù méjì

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 287

Ìgbìmọ̀ àwọn oníṣègùn èèbó lápapọ̀ èyítí ó ń fún wọn ní ìwé-àṣẹ àti tí ń ṣètọ̀ ìforúkọsílẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn ní United Kingdom, ti fún àwọn dókítà Nàìjíríà mẹ́rìnlá-dín-lọ́rìn-lé-nígba nínú Oṣù Karùn ún àti Oṣù Keje, ọdún 2022.

Itumọ eyi ni pe o kere ju, awọn dokita orilẹ-ede Naijiria mẹta n gba iwe-aṣẹ ni ọjọ kan ninu Oṣu Karun ati Oṣu Keje ọdun 2022, laibikita awọn igbesẹ ti Ijọba apapọ ti gbe lati dẹkun ijade awọn dokita ati awọn oṣiṣẹ ilera ni orilẹ-ede ninu bi awọn dokita akosemose ni orilẹ-ede ṣe n dinku.

Iye naa ko pẹlu awọn dokita miiran ti o jẹ ọmọ abinibi Naijiria ti ko  kẹkọ iṣegun ni Naijiria.

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, Nàìjíríà wà ní ipò kẹta ninu àwọn dókítà okeere tí ń ṣiṣẹ́ ní UK lẹ́yìn India àti Pakistan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button