Take a fresh look at your lifestyle.

Ìwọ̀n kan Àjẹsára HPV Tó Fún Ìdáábòbò Ààrùn jẹjẹrẹ- Àwọn amòye

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 310

Àjẹsára apillomavirus ìwọ̀n kán le dènà HPV, àti pé ìwọ̀n náà jẹ́ àfiwé ìṣètò ìwọ̀n lílo méjì,gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tuntun ṣe ríi.

Eyi jẹ ni ibamu si Ẹgbẹ Igbimọ to n pese Imọran Ilera lori ajẹsara ti ajọ to n risi ilera agbaye, ti ṣalaye pe, eyi le jẹ aluyọ lori idena arun naa, paapaa julọ ti awọn ọmọbirin to pọ diẹ ba le ri gba .

Awọn ile-iṣẹ fun Iṣakoso ati Idena Arun ṣapejuwe HPV bi kokoro ti o n  fa aarun jejẹrẹ si ara.

O salaye pe HPV jẹ arun ibalopọ ti o wọpọ julọ,o ṣafi kun pe awọn eniyan mẹtale-logoji miliọnu ni o ni HPV ni ọdun 2018,ti awọn ọdọ ti ko ju ogun ọdun lọ si pọju ninu wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button