Àwọn ọmọdé tí ó ní ààrùn jejerẹ ní Sudan tí ń gbé ní ilé ńlá kan tí a npè ní “Ìrétí wà nínú wa” ní olú-ìlú Khartoum, kò sọ̀rètí nù fún ọjọ́ iwájú.
Wọ́n wá láti oríṣiríṣi ìlú ní orílẹ̀-èdè naa ni Ìlà Oòrùn Áfíríkà, wọn sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àtìlẹ́yìn ẹgbẹ́ “A Ṣe Gbogbo Wà” ti o gbe bukaata oúnjẹ àti ìtọ́jú wọn.
Yasir Ali,ọmọ ọdun mẹwa kan jẹ akọkọ lati agbegbe North Darfur,awọn ẹbi rẹ kuro ni ilu Fashir lẹhin ti o bẹrẹ si ni maa jẹ irora ninu ara rẹ, nigbati wọn de Khartoum wọn dari wọn si ile nla naa.
Lakoko Ramadan, Ile-iṣẹ Ifowosowopo ati Iṣọkan orilẹ-ede Tọki (TIKA) ṣeto iftar ti wọn si n pese ounjẹ fun ogoji ọmọde ti o ni aarun jẹjẹrẹ ti wọn wa ninu ile nla naa.
Ikan lara awọn ọmọ naa, Muhammed Ibrahim ti bẹrẹ chemotherapy ati pelu aisan rẹ; ó ní òun fẹ́ di awakọ̀ òfuurufú nígbà tí òun bá dàgbà tí ohun yoo sì mọlu káàkiri.
Leave a Reply