Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti rọ àwọn olùdìbò tó yẹ ní Federal Capital Territory (FCT), Kano àti Rivers láti kópa nínú ìdìbò ní ọjọ́ Àbámẹ́ta láìsí ìbẹ̀rù, ó ń ké sí àwọn òṣèlú láti yẹra fún ìwà ipá àti ìwà ìgbónára.
Nínú ìkéde kan tí Olùdámọ̀ràn Pàtàkì fún Ààrẹ lórí Ìròyìn àti Ìlànà, Ọ̀gbẹ́ni Bayo Onanuga, Ààrẹ Tinubu gbóríyìn fún àwọn olùgbé FCT, Kano àti Rivers fún ìmọ̀ wọn nípa ìlú, ó sì sọ pé àwọn ìdìbò náà yóò fi ìfẹ́ àwọn ènìyàn hàn àti pé ìjọba tiwantiwa yóò jinlẹ̀ sí i.
Ààrẹ náà pàṣẹ fún àwọn ilé iṣẹ́ ààbò láti ṣe iṣẹ́ pẹ̀lú ìfaradà àti ìmọ̀ láti dáàbò bo ìgbẹ́kẹ̀lé ìlànà ètò ìdìbò naa.
Ààrẹ Tinubu tún bẹ Ìgbìmọ̀ Ìdìbò Orílẹ̀-èdè Olómìnira (INEC) ti Nàìjíríà láti gbé gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ láti mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo ènìyàn lee pọ̀ sí i nínú ìdìbò nípasẹ̀ yiye oruko wo kí a to bere ibo didi ní àkókò tó yẹ, àwọn ìlànà ìdìbò láìsí ìṣòro, ìdìpọ̀ pípéye àti ìgbéjáde àwọn èsì ní kíákíá ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Ìdìbò ọdún 2026.
Ó rọ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, àwọn olùdíje àti àwọn olùtìlẹ́yìn wọn láti yẹra fún ìwà ipá, ọ̀rọ̀ ìkórìíra àti ìṣe tó lè ba ìwà rere ìdìbò jẹ́.
Ààrẹ náà pe àwọn olùdìbò, àwọn ilé iṣẹ́ ààbò àti àwọn òṣìṣẹ́ ìdìbò láti hùwà ní ọ̀nà tó tọ́, ó tẹnu mọ́ ọn pé ìjọba tiwantiwa máa ń gbèrú jùlọ ní àyíká ìdákẹ́jẹ́ẹ́, ìfaradà àti ọ̀wọ̀ fún ara wọn.
Ààrẹ Tinubu tún kìlọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ ààbò lati lòdì sí ìwà aseju àti ìhalẹ̀mọ́ni, ó tẹnu mọ́ ọn pé ipa òfin wọn ni láti dáàbò bo ẹ̀mí àti dúkìá, láti dáàbò bo àwọn olùdíbò àti láti pa ofin mimọ́ ìdìbò mọ́.
Igbimọ Idibo ajọ INEC, yoo ṣe idibo ni awọn igbimọ agbegbe mẹfa ti FCT, ati awọn idibo ibo-keji ni awọn agbegbe Ahoada East II ati Khana II ti Ipinle Rivers, ati ni awọn agbegbe Kano Municipal ati Ungogo ti Ipinle Kano.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san