Igbákejì Ààrẹ Shettima padà sí Abuja lẹ́yìn ìjíròrò lórí ọrọ̀ ajé
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Igbákejì Ààrẹ Kashim Shettima ti padà sí Abuja lẹ́yiịn ọ̀sẹ̀ kan gbáko ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ àti èròńgbà ọrọ̀ ajé sí Guinea-Conakry àti Switzerland.
Igbakeji Aarẹ Shettima gunlẹ si abala Aarẹ ti papakọ ofurufu kariaye Nnamdi Azikiwe ni owurọ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinle-logun, lẹyin ti o lọ ṣoju Aarẹ Bọla Tinubu nibi igori ijọba Aarẹ Guinea, Mamadi Doumbouya, ti o si tun n ṣadari awọn aṣoju Naijiria lọ sibi Apejọ Apero Ọrọ Aje Agbaye ẹlẹekẹrindin-lọgọta (WEF), ọlọdọọdun ni Davos.
O sọ pe Naijiria ti gbapo iwaju rẹ pada lagbaye ati ninu ilana ifọrọjomitoro ọrọ Ẹkun.
Igbakeji naa wa fikun un pe, irin ajo naa wa lara atunṣe ipinnu Naijiria si atilẹyin Ẹkun ni Iwọ oorun Adulawọ ati ifọkansi lati ṣatunṣe lori ọrọ aje labẹ agbekalẹ Atunṣe Ireti ti Tinubu.
Igbakejio Aarẹ fi Abuja silẹ lọ si Conakry ni ọjọ Aiku to kọja, nibi ti o ti kopa ninu igori ijọba Aarẹ Doumbouya, ti o si n tun fidi ipo adari mulẹ ninu ECOWAS, ti o si tun ọna tuntun lelẹ fun ifọwọsowọpọ ọna meji lori ọgbin ati atunrọ.
Lati Guinea-Conakry, Igbakeji Shettima kọja si Davos, Switzerland, nibi ti o ti ṣadari Aṣoju Naijiria ni WEF 2026.