Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrùn ibà Dengue ń gbilẹ̀ ní Sokoto, tí ẹ̀mí kan sì lọ síi

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

17

Ilé iṣé tí ń rí sí ìmójútó àti ìdènà àjàkálẹ̀  Ààrùn ní Nàìjíríà (NCDC), ti jábọ̀ pé wọ́n ti fura sí ènìyàn mọ́kàndín-lógún tó ní ààrun ibà dengue nínu oṣù kọkànlá 2025, pẹ̀lú àwọn mẹ́f̀a tí ẹ̀mí wọn ti lọ síi, tí ìpínlẹ̀ Sokoto sì jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ṣoṣo tó ní ààrùn náà lásìkò náà.

Eleyi di mimọ nipasẹ alaye kan ni Ọjọbọ. NCDC sọ pe awọn ijọba ibilẹ meta (LGAs) ni ipinlẹ Sokoto  — Gusu Sokoto, Ariwa Sokoto ati Wurno — ni afurasi kan okere ju.

Ile iṣẹ eleto ilera sọ pe ẹmi to lọ si wa lara awọn iṣẹlẹ ti wọn ti fi to wọn leti tẹlẹ, ti ẹyi fa idẹruba aarun yii ti o jẹ eyi ti yanmuyanmu n ko kiri.

Lapapọ, ile iṣẹ naa ni laarin osu kinni si ikọkanla 2025, Naijiria ti ni ẹẹdẹgbẹrin- o –le-aarunle-lọgbọn afurasi to ni aarun dengue jakejado ipinlẹ marun ati ijọba ibilẹ mẹtadin-logun, pẹlu awọn eniyan mọkandin-logun-le-nigba to ti ni aarun naa, ti eniyan meji si ti jepe ọlọrun. Eleyi ṣe afihan bi aarun naa ṣe burujai si (CFR).

“Ipinlẹ Edo ati Sokoto ni o ni ida mẹrindin-laadọrun awọn afurasi, ti Edo nikan si ni awọn afurasi mẹtadin-logoji –le-lẹẹdẹgbaata ati mejidin-nigba awọn eniyan ti wọn ti fidiẹ mulẹ pe wọn ti ni aarun naa,” o sọ bayii.

Ile iṣẹ naa tun wa sọ pe awọn larin eniyan ọdun mọkanle-lọgbọn si aadọta ọdun ni aarun naa n mu julọ, leyi ti o jẹ ida mẹtale-logoji ati diẹ ninu ọgọrun, ti wọn si jẹ ọkunrin ati obinrin.

NCDC wa rọ awọ ọmọ Naijiria lati gbe igbesẹ idena rẹ ki wọn o si gba ile iwosan lọ kiakia ti wọn ba ti ri awọn ami iba dengue.

Aarun naa maa n mu iba to le dani, ori fifọ to burujai, ara riro, inu didaru ti n mu eebi lọwọ,ati kokoro. Eyi ba le ni, o le yọri si ẹjẹ dida, ki awọn eroja inu maa ṣiṣẹ ati iku.

Bi a ṣe le dena rẹ ni, kia maa jẹ ki omi rẹgun sibi kankan, titun ibi ti ẹfọn ba wa ṣe, lilo awọn eroja ti awọn kokoro kofẹẹ,  wiwọ awọn aṣọ ti yoo daabobo ara ati sisun labẹ nẹeti ti wọn ti fin oogun ẹfọn si.

 

Comments are closed.

button