Take a fresh look at your lifestyle.

Peter Obi darapọ̀ mọ́ ADC fún ìdìbò ọdún 2027

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

84

Olùdíje fún ipò Ààre ti ẹgbẹ́ Labour ní ọdún 2023, Ọ̀gbẹ́ni Peter Obi, ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ African Democratic Congress (ADC), ẹgbẹ́ òṣèlú ìṣọ̀kan, fún ìdìbò gbogbogbòò 2027.

Obi kede ifi ẹgbẹ rẹ silẹ ni Ọjọọru, ọjọ kọkanle-lọgbọn, Oṣu kejila, ni ilu Enugu, o sọ pe igbese naa waye nipasẹ igbafun isọdọtun fun iyipada ati fun gbigba Naijiria kuro ninu awọn italaya to n koju rẹ lọwọlọwọ.

“A n pari ọdun yii pẹlu ireti pe ni 2026 a o bẹrẹ igbala,” Obi sọ bayii. O tun wa fidi ipinnu iṣọpọ lati daabobo ijọba tiwantiwa mulẹ, o fi kun bakannaa pe, “A ko ni faaye gba eeru ninu idibo pẹlu ni lilo gbogbo ọna to tọ ni 2027.”

Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra tẹ́lẹ̀ rí wá rọ àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ alátakò jake jado orílẹ̀-èdè  láti fìmọ̀ṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ẹbí kan lábẹ́ adarí Ààrẹ Sẹnetọ̀ tẹ́lẹ̀ rí  o tun jẹ Alaga gbogbogboo ẹgbẹ ADC , Sẹ́nétọ̀ David Mark, láti bẹ̀rẹ̀ẹ ètò tuntun fún orílẹ̀-èdè.

Ọpọlọpọ awọn gbajugbaja oloṣelu lo wa sibi ijọko naa, ara wọn ni Sẹnetọ David Mark; Gomina Ipinlẹ Sokoto nigba kan ri, Ṣenetọ Aminu Tambuwal; awọn gomina tẹlẹ ri lati Guusu-Ila-oorun; ati awọn olori ẹgbẹ miiran.

Awọn ti o tun wa nibẹ ni, igbakeji olori Ile Igbimọ Aṣoju, Emeka Ihedioha; Awọn Sẹnetọ, Ben Obi, Victor Umeh, Tony Nwoye, Gilbert Nnaji, Enyinnya Abaribe, ati Sam Egwu; Oloye Onyema Ugochukwu; ati awọn ti wọn si jẹ ọmọ ile igbimọ Aṣofin ati awọn ti wọn ti fi igba kan jẹẹ ri.

Idarapọ yii jẹ igbesẹ pataki lori igbaradi fun idibo ọdun 2027, gẹgẹ bi awọn ẹgbẹ alatako ṣe n gbiyanju lati fese rinlẹ.

Comments are closed.

button