Lára àwọn ètò láti ṣàmì ayẹyẹ Àyájọ́ Àkọ́kọ́ irú ẹ̀ ti Agbófinró ní ìpínlẹ̀ Gombe, Adarí Agbófinró ti pèsè ètò ìwòsàn ọ̀fẹ́ láti ṣàtúnṣe lórí ìlera àwọn ará ìlú àti láti túnbọ̀ fìdí àjọṣepọ̀ láàrin Agbófinró Nàìjíríà àti àwọn agbègbè múlẹ̀.
Adari Agbófinró, ti Agbegbe ipinlẹ Gombe, CP Yahaya wa rọ awọn aladugbo lati lo anfaani naa daradara.
Ijade agbegbe yii waye nipasẹ ifisọkan Agbofinro Naijiria ti kii ṣe lati ṣedaabo bo fun ẹmi ati dukia nikan bi ko ṣe lati ṣagbelarugẹ igbe aye alaafia awọn ara ilu.
Ẹgbẹ naa wa ni pẹlu eto iwosan ọfẹ yii, ohun n ṣafihan ifẹ ati ilaanu loju Agbofinro, nipa erongba wọn ti o fojusun awọn eniyan, ti o si fi kun un pe eto naa waye pẹlu ajọṣepọ àwọn oṣiṣẹ ilera akọṣẹmọṣẹ.
Awọn itọju ọfẹ fun awọn eniyan naa ni iṣayẹwo ẹjẹ riru, ayẹwo ṣuga, ayẹwo aarun kogboogun, ayẹwo aarun jẹdọjẹdọ B Ati C , pinpin awọn ohun itọju pataki, ati idanilẹkọ lori ilera.
Eto iṣaanu yii n waye ni awọn ibi meji to jẹ bonkẹlẹ ni ipinlẹ Gombe ; ni iwaju Aafin Emir ti Gombe, Abubakar Shehu Abubakar Kẹta ati Ibugbe awọn Agbofinro, Gombe.