Take a fresh look at your lifestyle.

Agùnbánirọ̀ Pín Ohun Èèlò Àlejò Obìnrin Fún Àwọn Ọmọbinrin Ní Ìpínlẹ̀ Kogi

196

 

Agùnbánirọ̀ kan, ọmọ ẹgbẹ́ àti Olùdásílẹ̀ ètò ‘Pet’ ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Victoria Toluwaloju, ti pín ohun èèlò àlejò Obìnrin fún ọmọ ilé ìwé tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó dín mẹ́tàlá kaakiri àṣàyàn ilé ẹkọ gíga márùn ún ìpínlẹ̀ Kogi fún ìwúlò àlàáfíà nǹkan oṣù wọn àti ìgbé ayé tó dára.

Ilé ìwé tó jẹ ànfààní náà niyi; Crowther Memorial College, Government Girls’ Secondary School, Universal Basic Education Trinity Secondary School ati Muslim Community Secondary School tí gbogbo wọn wà ní agbègbè Lokoja.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bìnrin náà ní wọ́n tún kọ́ nípa ẹ́kọ́ nípa ohun tí wọ́n fẹ́ dà lọ́jọ́ ọ̀la, ìkọ́raẹni àti ṣíṣe ìmọ́tótó nǹkan oṣù. Ó tún rántí àwọn àkàndá ẹ̀dá tí ara pè níjà bíi adití nípa lílọ sí ilé ìwé wọn ní Lokoja ti wọ́n sì tun kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.

Arábìnrin Toluwaloju ṣe àlàyé bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe èyí fún àwọn ọmọbìnrin àti pàápàá bí àkọmọ̀na Agùnbánirọ̀ ti sọ pé: Iṣẹ́ ìsìnlú àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button