Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ Nàìjíríà Lulẹ̀ Nínú Ìdíje Tẹ́níìsì Ilẹ̀ Adúláwọ̀

162

 

Ikọ̀ Nàìjíríà subú jáde nínu Ìdíje Tẹ́níìsì àgbáyé – International Table Tennis Federation (ITTF) ti Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní ìlú Tunis, orílẹ̀-èdè Tunisia.

Ikọ̀ Canaan Queens ti Calabar tó ń sojú fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kọ́kọ́ fìdí rẹmi pẹ̀lú ayò òdo sí mẹ́ta (0-3) sí ọwọ́ ikọ̀ àwọn obìnrin PETROJET ti orile-ede Ẹ́gíptì ní àbàlá tó kángun sì àsekágbá ìdíje ní gbọ̀ngàn El-Menzah Sports ni Tunis ní ọjó Ajé.

Ikọ̀ kan ṣoṣo tó sojú fún Nàìjíríà tí Fatimo Bello, Janet Effiong, Cecilia Otu-Akpan àti Hope Udoakati sáájú ti kọ́kọ́ gbo ewúro sójú alátakò wọn láti orílẹ̀-èdè Tunisia àti Madagascar ní ìsọ̀rí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìdíje. Ní àbàlá tó gbẹ̀yìn ìsòrí ni wọ́n tó wá subú sì ọwọ́ ikọ̀ Zamalek ti Egipti pẹ̀lú ayò òdo sí mẹ́ta (0-3), ti wọ́n si ṣe ipò Kejì ní ìsòrí wọn, kí wọ́n tó wá subú ní àkótán sí ọwọ́ ikọ̀ àwọn obìnrin PETROJET.

Ní ti àbàlá àwọn Okunrin, ikọ̀ mẹ́sàn án ló sojú láti orílẹ̀-èdè ,Egypt, Algeria, Ethiopia, Tunisia, Madagascar, Congo DR àti Cote d’Ivoire, pelu iko Egypt’s ENPPI tí ìfe ẹ̀yẹ àna wà lọ́wọ́ wọn.

Ìdíje ìfe ẹ̀yẹ ITTF Ilẹ̀ Adúláwọ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjó Ìṣẹ́gun ní ìlú Tunis bákannáà.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

 

Comments are closed.

button