Alága àjọ Association for the Advancement of Family Planning (AAFP) ni Nàìjíríà, Dókítà Ejike Oji ti sọ pe ètò Ìfètòsọ́mọbíbí a máa jeki Ọmọ dàgbà dáradára, a máa dènà ọmọ rándanràndan.
Ọ̀gbẹ́ni Oji sọ eyi nibi ìfọ̀ròwánilẹ́nuwò ní Abuja ni ọjọ Aje pé, ọpọlọ ọmọ a máa dàgbà ni kété ti a bi ọmọ ni ẹgbẹ̀rún ọjọ́ àkọkọ ti a bíi. Ọmọdé ti kò jẹ oúnjẹ to se ara lóore a máa dènà ìdàgbàsókè to múyán lórí.
Ìkùnà láti se ètò Ìfètòsọ́mọbíbí a máa ṣọ ọmọ di ráunràun, a tún máa mú ki ọrọ̀ òbí búrẹ́kẹ́ sí, a tún jẹ ki ìgbésí ayé ọmọ dára síi bi Dókítà Oji se sọ.
Ó fi kun pé ìlànà ètò ọrọ̀ ajé ìjọba yóò máa bọ́ rẹ́lẹ̀ sí ni àyàfi ti wọ́n bá gbájúmọ́ ìlọsíwájú ètò yí dáradára.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san