Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti gúnlẹ̀ sí Ìlú Accra olú ìlú Orílẹ̀-èdè Ghana fún ayẹyẹ ìbúrasípò fún ààrẹ tí wọ́n dìbòyàn, John Dramani Mahama
Ààrẹ Tinubu gbéra láti pápákọ̀ òfurufú ti àgbáyé Muritala Muhammed tí ó wà ní ìlú Eko ní déédé agogo mẹ́rin kọjá ogún ìsẹ́jú tí ó sì gúnlẹ̀ si pápákọ̀ òfurufú Kotoka ní ìlú Accra ní déédé agogo márùn-ún kọjá ìsẹ́jú márùn-ún níbiti alákòsóo isẹ́ ààrẹ Orílẹ̀-èdè Ghana, Ọnọrébù Julius Debra ti gba àlejò rẹ̀
Nígbà tí ó wà ní ìlú Ghana, Ààrẹ Tinubu, tí ó jẹ́ alága àjọ ECOWAS yóò kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú àwọn adarí Orílẹ̀-èdè Adúláwò míràn láti kópa níbi ayẹyẹ ìbúrasípò Mahama pẹ̀lú igbákejì rẹ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n Naana Opoku-Agyemang
Mínísítà kejì fún ọ̀rọ̀ Ilẹ̀ Òkèèrè, Arábìnrin Bianca Odumegwu-Ojukwu àti àwọn ènìyàn pàtàkì míran ni ó kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú Ààrẹ