Take a fresh look at your lifestyle.

Ramadan: Ọba Nupe rọ àwọn ọlọ́jà láti mówó oúnjẹ wálẹ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

253

Alhaji Yahaya Abubakar, tí ó jẹ́ Etsu Nupe, (Ọba àwọn Nupe ní Aríwá Àringbùngbùn Nàìjíríà) ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn ọlọ́jà lórílẹ̀-èdè láti máá fowó kún owó oúnjẹ àti àwọn èròjà oúnjẹ mìíràn bí oṣù Ààwẹ̀ ṣe ń bọ̀ yìí. Ramadan jẹ oṣu mimọ ti awọn Musulumi maa n gba aawẹ ti wọn ko ni jẹun, mu ati awọnnnkan miiran lati owurọ titi di irọlẹ fun oṣu kan gbako. Alhaji Abubakar, ẹni ti o tun jẹ alaga igbimọ awọn lọbalọba ni ipinlẹ Niger, pe ipe yii nigba ti o n ba awọn oniroyin sọrọ laafin rẹ, ní ijọba ibilẹ Bida ti ipinlẹ Niger, ni ọjọ Abamẹta.

O wa gba awọn ọmọ Naijiria nimọran lati jẹ oluranlọwọ fun awọn alabagbe wọn bi Ojiṣẹ nnla ọlọrun  ṣe kọwa ninu ẹsin Islam ati awọn ẹkọ Islam miiran.

Etsu Nupe, ṣalaye pe o yẹ ki awọn ọlọja nibẹru ọlọrun ki wọn o si ṣe owo wọn bi o ṣe tọna ninu ofin Islam ti o si tun ṣalaye pataki riran awọn alabagbe wa lọwọ

Etsu Nupe sọ pe awọn olutaja ye ki wọn ro ti ẹni ti ko ni nnkankan ki wọn o si mowo ọja wọn walẹ, paapaa julọ awọn eroja ounjẹ, lati je ki awọn eniyan le ra wọn.

Comments are closed.

button