Nàìjíríà, Bulgaria yóò túnbọ̀ fìdí ètò ẹ̀kọ́ ààrin wọn múlẹ̀ si
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Mínísítà fún ètò Ẹ̀kọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Tahir Mamman, ti sọ pé Nàìjíríà ti ṣetán láti túnbọ̀ fìdí àjọṣepọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Bulgaria múlẹ̀ ní abala ètò ẹ̀kọ́.
Minisita naa wa pinnu pe wọn yoo ṣe eto isọdọtun adehun to wa laarin Naijiria ati Bulgaria ni kiakia.
ỌjọgbọnTahir sọ eyi di mimọ laipẹ, ni ọfiisi rẹ ni Abuja, nigba ti o gba Aṣoju pataki ti orilẹ-ede Bulgaria si Naijiria, Yanko Yordanov lalejo.
Gẹgẹ bi Minisita ṣe sọ, Ẹkọ Fafiti jẹ ohun kariaye, ti Naijiria si ṣetan lati fọwọsowọpọ lori iṣewadi, ati ṣiṣe pasipaarọ awọn eto pẹlu awọn orilẹ-ede kaakiri agbaye.
Ọjọgbọn Tahir wa n fi da Asoju naa loju pe Naijiria ṣetan lati tẹsiwaju lori ajọṣepọ ti yoo ṣe awọn mejeeji lanfaani.
Nigba ti o n fesi, Minisita ipinlẹ fun eto Ẹkọ, Dokita Yusuf Tanko Sununu wa n ṣalaye fun aṣoju naa pe awọn Fafiti Naijiria ti ṣetan lati fọwọwewọ pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ jakejado agbaaye ni oniruuru iṣẹ ọmọ niyan, ti o si fi kun un pe “Bulgaria ti ju bi o ṣe wa tẹlẹ lọ, kaabọ si itẹsiwaju lori ajọṣepọ to ti wa tẹlẹ, paapaa julọ ni isọri iṣe ọgbin ati oogun.”