Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrùn ẹranko: Kọmíṣọ́nà fún ètò ìlera kìlọ̀ fún ìbẹ́sílẹ̀ ní Cross River

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

197

Wọn ti rọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Cross River ní Gúsù Nàìjíríà láti jẹ́ kí ìmọ́tótó jẹ wọ́n lógún àti ìtún àyíká ṣe nítorí ìbẹ́sílẹ̀ ààrun ẹranko tí ó ti gbẹ̀mí ẹnìkan.

Kọmíṣọ́nà fún ètò ìlera, Dokita Egbe Ayuk, ti o ṣe ikilọ yii ni Calabar, olu ipinlẹ naa, sọ pe wọn ri eni to ni aarun ẹranko yii ni ijọba ibilẹ Obubra, Aringbungbun agbegbe Cross River.

Ayuk ṣalaye pe ile iṣẹ ijọba apapọ pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ile iṣẹ to ku ṣe iwadi ti wọn si jabọ, pe  “idanomọ fun ẹni ti o di oloogbe naa – o jẹ olugbe agbegbea Ejah ti ikọ kinni Osupong, ijọba ibilẹ Obubra ti wọn ri ni ile iwosan Fafiti ikọni ti ijọba apapọ Abakaliki, ipinlẹ Ebony, ti wọn si ti fidi rẹ mulẹ pe o ni aarun ẹranko.

O tun wa sọ siwaju pe ẹgbẹ naa Yoo ṣe, “akojọpọ awọn ohun elo aarun ẹranko, awọn nkan ti enu le jẹ ati awọn nnkan ti eniyan lefi daabo bo ara rẹ fun ile iwosan gbogbogboo ti Obubra ati awọn agbegbe miiran.”

 

Comments are closed.

button