Ẹgbẹ́ kan lábẹ asia Ẹgbẹ́ Àwùjọ Ará ìlú (CSOs), àti ètò ibùdó ilé ìwòsàn alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti gbìmọ̀ láti dá ìsọ̀rí tí yóò máa mójútó èto àwọn ilé-ìwòsàn, pàápàá jùlọ ní àwọn ìgbèríko.
Ninu alaye kan ti alaga ati akọwe ẹgbẹ naa, Bala Mohammad ati Peter Ibrahim Amfani, jọ buwọlu ti wọn si fi sita ni Ọjọọru, wọn ṣe ipinnu lati da isọri ti yoo maa ṣamojuto naa silẹ nibi ipade rẹ ti o waye ní Kaduna ti wọn si ti to wọn leti bi eto ilera ti mẹhẹ paapaa julọ ni awọn ijọba ibilẹ. CSOs wa sọ pe eleyi ni lati ṣatilẹyin fun ilọsiwaju atunṣe eto iṣẹ itọju jakejado orilẹ-ede.
Gẹgẹ bi ẹgbẹ naa ṣe sọ, idi ti wọn fi da isọri alamojuto naa silẹ ni lati ri pe awọn ara ilu ni anfaani si eto ilera to muna doko, ti owo rẹ ko jara lọ, paapaa julọ ni awọn igberiko.