Take a fresh look at your lifestyle.

Akọ̀wé gbogbogbòò rọ àwọn Dókítà, òṣìṣẹ́ elétò ilérà láti dúró sí Nàìjíríà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

381

Akọ̀wé gbogbogbòò, Ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tí ń mójútó ètò ààbò, Dókítà Ibrahim Abubakar Kana, ti ṣàlàyé pé ìjọba àpapọ̀ ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣàtúnṣe lórí abala ètò ìlera ní Nàìjíríà, tí ó ṣì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn Dókítà àti àwọn òṣìṣẹ́ elétò ilérà mìíràn láti máá fi orílẹ̀-èdè sílẹ̀ lọ ṣiṣé lórílẹ̀-èdè mìíràn.

Kana rawọ ẹbẹ yii nigba ti o n sọrọ nibi ayẹyẹ ifilọlẹ ipade igbimọ alaṣẹ apapọ, ẹgbẹ iṣoogun ni Naijiria (NMA), ní Abuja.

Akọ̀wé gbogbogbòò naa ti o figba kan jẹ alaga ayẹyẹ naa wa rọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ lati maa fi orilẹ-ede silẹ lọ ṣiṣẹ lorilẹ ede miiran nitori pe ijọba aarẹ Bọla Ahmed Tinubu to wa lori oye lọwọ bayii ti pinnu lati tun abala eto ilera ṣe, nigba ti o n sọrọ lori oun ti gbaye kan lọwọ bayii :“Japa syndrome”.

O wa sọ pe idi ipade naa ni lati gbimọ ati lati wa ọna abayọ lori iṣeto ilera ni Naijiria.

 

Comments are closed.

button