Gómìnà ṣe ìfilọ́lẹ̀ LOC Fún ìpàdé ìgbìmọ̀ àpapọ̀ lórí Àyíká
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Gomina Dikko Radda ti ìpinlẹ Katsina, ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ ìṣètò abẹ́lé (LOC), elénìyàn mọ́kànlá fún ìpade ìgbìmọ̀ àpapọ̀ lórí Àyíká, tí yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Katsina.
Akọwe fun ijọba ipinlẹ (SSG), Alhaji Abdullahi Faskari, ni o ṣe ifilọlẹ igbimọ naa, ni orukọ Gomina, ni ọjọ Ẹti, ni Katsina.
Faskari sọ pe ipade ipade igbimọ apapọ lori Ayika ẹlẹẹkẹtadin-logun yii yoo waye ni ọjọ kọkanla, oṣu kejila si ọjọ kẹrindin-logun, oṣu kejila 2023.
O wa fikun pe LOC yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu igbimọ oluṣeto gangan lati mọ iye awọn aṣoju ati awọn olukopa ti n bọ wa si Katsina fun ipade naa. Gẹgẹ bi o ṣe sọ, igbimọ naa yoo tun wa ati pese ibi to boju mu ti wọn a de si ati eto lilọ bibọ awọn asoju pẹlu awọn ti yoo kopa ninu ipade naa.
Akọwe fun ijọba ipinlẹ tun sọ pe awọn nnkan miiran ti awọn igbimọ naa yoo tun ṣe ni ipese eto ipolongo ati aabo fun ipade naa.
Faskari, tun sọ pe Kọmiṣọna ipinlẹ fun Ayika, Alhaji Musa Adamu-Funtua yoo jẹ alaga igbimọ LOC.
Leave a Reply