Take a fresh look at your lifestyle.

Sẹ́nétọ̀ Yari ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìtọ́jú ọjú fún àwọn aláìsàn ẹgbẹ̀rún kan ní Zamfara

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 209

Sẹnetọ Abdul’aziz Yari, ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìtọ́jú ojú àti iṣẹ́ abẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn aláìsàn ẹgbẹ̀rún kan ní ìpínlẹ̀ Zamfara.

Yari, ti n ṣoju iwọ oorun Zamfara ni ile igbimọ, ṣalaye lasiko ayẹyẹ naa ní ile iwosan gbogbogboo, ti Talata-Mafara, pe Vision Savers Eye Care Centre ni yoo ṣe eto naa.

Yari, ẹni ti alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) tigba kan ri, Alhaji Lawal Liman, ṣoju sọ pe agbekalẹ yii jẹ ọkan ninu ipinnu rẹ ni abala ilera.

O wa sọ pe eto naa waye lati ran awọn to ni ipa lara pẹlu ipeninija oju ṣugbọn ti ko ni agbra lati san owo itọju.

Awọn miiran yoo tun janfaani ni ijọba ibilẹ Anka, Bakura, Bukkuyum, Gummi, Maradun ati Talata-Mafara ninu ipele miiran ti n bọ.

Awọn agbalagba, awọn to ni ipalara, awọn obinrin, ati awọn ọmọde ni yoo janfaani naa.

 “Awọn ti yoo janfaani rẹ yoo gba itọju oju, iṣe abẹ, ati oogun lasiko eto naa,” o fi kun un.

Ninu ọrọ rẹ , Emir Talata-Mafara, Alhaji Bello Muhammad-Barmo wa ṣapejuwe agbekalẹ yii bii ohun ti wọn nifẹ si.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button