Ààrẹ Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu ti sọ pé Nàìjíríà ti ṣetán láti jọ ṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Saudi Arabia láti kojú ẹgbẹ́ oníjàgídíjàgan bíi Boko Haram, ISWAP, àti àwọn ẹgbẹ́ alákatakítí mìíràn.
Nigba ti o n sọrọ nibi apejọ Saudi-Africa ní Riyadh, Saudi Arabia, ní ọjọ́ Ẹtì, aarẹ Tinubu sọ pe Naijiria ti ṣetan bayii o, ti o si wa n fi da awọn oludokowo loju pe , wọn yoo ri ere to pọ.
Aarẹ Tinubu tun wa n mu da awọn ti wọn n gbero lati ṣe idokowo loju pe, aabo wa lori okowo wọn ni Naijiria.
Agbẹnusọ fun aarẹ, Ajuri Ngelale lo sọ eleyi di mimọ ni ọjọ Ẹti, ninu alaye kan ti o buwọlu.
Aarẹ Tinubu wa dupẹ lọwọ orilẹ-ede naa fun ọpọlọpọ agbekalẹ aanu ni Naijiria nipasẹ ibudo iranlọwọ ati itura ti Ọba Salman.
Lori ọrọ iyipada oju ọjọ ati ipa rẹ lori Afirika, aarẹ Tinubu sọ pe iyipada oju ọjọ ti fa ilẹ gbigbẹ ati omiyale gbogbo igba ni Naijiria ati ni awọn orilẹ-ede Afirika ti ko niye.
Leave a Reply