Adamawa yóò fún àwọn ọmọ bìnrin tó fẹ́ẹ̀ tó irínwó ẹgbẹ̀rún ní abẹ́rẹ́ àjẹsára láti dènà HPV
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé–iṣẹ́ tó ń mójútó ìdàgbàsóke ètò ìlera abẹ́lé ní ìpínlẹ̀ Adamawa, ti sọ pé òun gbìmọ̀ láti fún àwọn ọmọ bìnrin láti ọdún mẹ́sàn án sí ọdún mẹ́rìnlá tó fẹ́ẹ̀ tó irínwó ẹgbẹ̀rún ní abẹ́rẹ́ àjẹsára láti dènà Human Papilloma Virus (HPV,) tí yóò gbógunti àar̀ùn jẹjẹrẹ ẹnu ilé ọmọ.
Dokita Suleiman Bashir, alaṣẹ alaga ile-iṣẹ naa, sọ eleyii di mimọ ninu ifọrọ wanilẹnuwo pẹlu awọn oniroyin ni Yola.
Bashir sọ pe itaniji ati ajẹsara fun awọn omọ binrin lati koju kokoro naa n lọ lọwọ bayii ti yoo si lọ bẹẹ fun oṣu mẹta.
O wa fi kun un pe yiyan awọn ọmọ binrin ọdun mẹsan an si ọdun mẹrinla fun ajẹsara naa jẹ lati daabobo ati lati fun wọn lagbara lati le koju aarun naa.
Dokita Goni Abba, adari, ile-iṣẹ to n mojuto ilera ara ilu ni orilẹ ede Borno, ṣalaye pe ajẹsara ati idanilẹkọ ti bẹrẹ.
Abba tun wa sọ pe wọn ṣe ifilọlẹ ajẹsara naa ni ọsẹ to kọja, ni Abuja ti awọn aṣoju ipinlẹ naa ti o wa ni Abuja si ṣẹṣẹ pada, o tun wa sọ pe ile iṣẹ naa ni lati ṣe ipade fun igbesẹ ti o ba kan lori ajẹsara ni ipinlẹ naa.
Leave a Reply