Take a fresh look at your lifestyle.

Ìmúkúrò Àdínkù : Ààrẹ Tinubu ń ṣiṣẹ́ lórí ìrọ̀rùn – APC Amẹ́ríkà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 266

Alága fún ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress APC ní Amẹ́ríkà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Tai Balofin ti rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti gbàgbọ́ pé ààrẹ Bọla Tinubu, yóò ṣiṣẹ́ lórí ìrọ̀rùn tí yóò bomi sí títa ríro àyọkúrò owó epo ilẹ̀.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Balofin tí ó sọ èyí ní ọjọ́ Àìkú,ní Abuja,fikún un pé ìpeniníjà tó wáyé lórí ìyọkúrò yìí yóò tó di oun ìgbàgbé.

Fún ìdí èyí, ó wá rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ní sùúrù fún ìjọba Tinubu lóríi àyọkúrò àdínkù owó epo ilẹ̀,pé fún dáradára orílẹ̀-èdè ni.

Mo kàn fẹ́ rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ní sùúrù kí wọ́n sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yé wọn,” Bolofin sọ báyìí.

Alaga ẹgbẹ APC ní Amẹrika, sọ pé bótilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ń gbé lókè òkun, àwọn rí ìnira tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú,nígbà tí ó ń rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ní sùúrù fún ìjọba.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button