Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Anambra : Igbákejì ọ̀gá Agbófinró fi ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ dá àwọn agbègbè lójú

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 166

Igbákejì ọ̀gá Agbófinró, AIG, Ọ̀gbẹ́ni Tony Olofu tí ó ń ṣojú olú ilé-iṣẹ́ agbègbè kẹtàlá, ní Ukpo, ìpínlẹ̀ Anambra, ti fi dá àwọn agbègbè ní ìpínlẹ̀ náà lójú pé òun yóò ṣèrànlọ́wọ́ fún wọn.

AIG ṣe ìfidánilójú yìí nígbà tí ó ń ṣe àbẹ̀wò sí Ọba Ukpo, Igwe Dókítà Robert Eze.

Olofu tọ́ka sí pé agbègbè ti ṣe àtúnṣe lórí ètò ààbò tí wọ́n ṣe fún oríṣiríṣi agbègbè láti pèsè ìmójútó tó múnádóko, láti tún fìdí ìṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn elétò ààbò míràn múlẹ̀ lágbègbè náà.

Gẹ́gẹ́ bí AIG ìsọ̀rí kẹtàlá ṣe sọ, àbẹ̀wò náà jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà ìfojúsí ṣíṣe àjọṣepọ̀ tó jinlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó nííṣe lágbègbè, fún ààbò àwọn ará ìlú àti ìlú.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button