Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọ̀rọ̀ – Ọ̀rọ̀ ìdágbére Láti Ẹnu Ààrẹ Muhammadu Buhari, Ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà.

0 307

Ẹ̀yin ènìyàn mi lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, àti àwọn tó ń gbé káàkiri àgbáyé.

Mò ń bá a yín sọ̀rọ lóní, èyi tó jẹ́ iṣẹ́ mi tí ó gbẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bi Ààrẹ Ìjọba tiwa-n-tiwa tí a yàn sípò gẹgẹ bi ààrẹ orilẹ-ede Nàìjíríà,

Mo tún dúpẹ́  lọ́wọ́ Ọlọrun ati  awọn ọmọ orilẹ eniyan Naijiria.

Lónìí tí à ń ṣe àjọyọ̀ ayẹyẹ ìgbà tuntun lati ìjọba to wa tẹ́lẹ̀ ati èyí ti a ṣẹsẹ yan sipo nínú ìrìn-àjò iduroṣinṣin wa lati mu ilọsiwaju ati atilẹyin bá ijọba tiwantiwa orilẹ-ede Nàìjíríà.

Ni ọdun yii, lati rí idibo to kaju oṣuwọn .ni eyi to gbe ohunjẹ fẹgbẹ-gbawobọ ni  eyi to ṣe afihan pe ijọba tiwantiwa wa ti n dara sí i .

Gẹgẹ bi orilẹ-ede kan,a gbọdọ ní igbagbọ  ninu eto  ilana idibo wa, nipa lati ri i pe orilẹ ede Naijiria gbe igbá oroke laaarin àwọn akẹgbẹ rẹ.

Ètò Ìjoba Tiwa-n-tiwa fun wa ni anfaani lati sse atunse si  awọn aiṣedeede ti a rii, ti o jẹ ki diẹ ninu awọn oludije ati awọn ẹgbẹ oselu ti ko faramọ èsì ìdìbò pẹ̀lú abajade lati lọ si ile-ẹjọ.

Laibikita abajade awọn ẹjọ oriṣiriṣi, Mo rọ gbogbo awọn ẹgbẹ ti ọrọ kan lati gba ipinnu ti awọn ile-ẹjọ ṣe, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu  Ijọba to jawe olubori lati gbe  orilẹ-ede Naijiria de ibudo ògo.

Mo kí gbogbo olùdíje tó kópá nínú ìdíje ààrẹ ọdụ́n yìí fún ìgbagbọ tí ẃọn ní sí ìdájó ilé ẹjọ́.

Lákòkóò ìpolongo, orísirísi àríyànjiyàn ló jẹyọ lóri bí a ṣe lè mú ìdàgbàsókè bá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà , ṣùgbọ́n inú mi dun pé, eyi ko yọri sí ìjà.

Gẹgẹ bi alakoso ati adari orilẹ-ede Nàìjíríà, Mo pe gbogbo wa lati mu agbara ti ẹni-kọọkan wa ní, agbara isokan wa, lati jẹ ki orilẹ-ede Nàìjíríà dara si i.

Arákùnrin mi, ọrẹ mi ati alabaṣiṣẹpọ mi ninu oṣelu láti bi ọdun mẹwaa sẹyin – Asiwaju Bola Ahmed Tinubu – Mo ki ọ ku orire fún jijawe olubori, eyi ti o jẹ itara lati mú orilẹ-ede Naijiria wà nínú àwọn orilẹ-ede ti yoo wa niwaju laarin gbogbo orilẹ-ede to ku lagbaaye.

Lóòótọ́ lo ti sise fun ojo oni, Ọlọ́run sì ti dé akitiyan rẹ ládé.

Laarin gbogbo awọn oludije, Ìwọ ni olùdíje tó dára jù àti pé àwọn ọmọ Naijiria ti yan ẹni tó tọ́.

Ọdun mẹjọ ti o kọja yii jẹ iriri ti inu mi dun si lati ri orilẹ-ede Nàìjíríà bo ṣe n gbòòrò síi, ti alaafia ati aabo si wa pẹlu.

Ètò ọrọ̀ ajé orilẹ-ede Nàìjíríà ti dara sii latari awọn eto idagbasoke oriṣiriṣi ti a gbe kalẹ lati ríi daju pe eto-ọrọ aje wa n gbèrú síi lasiko awọn iṣẹlẹ to mu iṣubu bá eto-ọrọ aje agbaye.

Gbogbo wa la ranti awọn iṣoro ti o deba ọrọ aje agbaye laarin ọdun 2020 sí 2022 latari arun COVID-19. Bi a ṣe koju arun naa tun jẹ ilana ti o dara julọ ní agbaye.

Síwájú sí i, a fún àwọn tí kò rí jájẹ àti àwọn to n gb ní ìgbèríko lorilẹ ede  Nàìjíríà ni anfaani lati le ṣiṣẹ, a pèsè oúnjẹ púpọ̀ sí i fún miliọnu eniyan to n gbé ní abúlé, a sì fún àwọn obìnrin wa  ní ánfààní láti máa gbọ́ bùkátà ara wọn.

A ran àwọn ọdọmọkunrin ati awọn obinrin ti o wa ni awọn ile-iṣẹ aladaani  lọwọ. Ìjọba wa tun pese agbegbe ti o dara lati  ṣiṣẹ fun àwọn aladaani.

Àwọn Ile-iṣẹ aladaani fi ibasepọ to danmọran han si Ijọba wa lati kọjú iṣoro ọrọ aje.

Nínú awọn igbesẹ ti a gbe lati ṣe atunṣe eto-ọrọ aje, a gbiyanju àwọn igbesẹ to nira kọọkan, ṣugbọn pupọ ninu awọn igbesẹ naa lo yori si daadaa. Díẹ̀ ninu awọn igbese naa mu irora ati ijiya fun igba diẹ, ti Mo fi tọkàntọkàn tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ orilẹ-ede Nàìjíríà, ṣugbọn awọn igbese naa ni a ṣo eso rere fun gbogbo wa lorilẹ-ede yii.

Òógùn wa lati rii daju pe gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede Nàìjíríà n gbe igbe aye alaafia àti aabo to péye yori si rere. Bi mo ṣe pari akoko mi ni ọfiisi ààrẹ, ọlọrun ti fún wa ṣe, ati saseyọri lori  awọn iwa ajinigbe, olè, ipaniyan, aabo ti ko peye .

Lati ríi daju  pe gbogbo àwọn nkan yii di ohun igbagbe, ẹ jẹ ki gbogbo wa maa ṣọra, ki a si fọwọsowọpọ pelu àwọn ajọ eleto aabo lati jẹ ki aabo ti ko fẹsẹ mulẹ di ohun igbagbe ni agbègbè wa.

Titi di isinsin yii, inu mi bajẹ fun awọn ọmọ wa ti o ṣi wa ni ahamọ àwọn oniṣe laabi, mo ba awọn obi, awọn ọrẹ ati ibatan wọn  kẹdun, mo si ni igbagbọ pe awọn oṣiṣẹ eto aabo  yoo gbiyanju lati ri pe gbogbo wọn ri ominira gba.

Ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà, ẹ mọ bí gbigbogun ti iwa ibajẹ  lorílẹ̀-èdè ṣe gbilẹ lọ́kàn mi tó.

Mo tun fẹ lo anfani yii lati dupẹ lọwọ ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti o ṣe atilẹyin fun ìjọba wa ati igbiyanju wọn lori mimu orilẹ-ede Nàìjíríà de ibi gíga .

Mi ò lè gbàgbé àwọn ẹgbẹẹgbẹrun àwọ́n tó gbàdúrà fún mi nígbà ti mo ṣe àìsàn ní àsìkò Ijọba àkọ́kọ́ mi ní ọ́fíìsì. Mò ń gbadura nigba gbogbo fun un yin ati fun Naijiria lati ma lọ iwaju sí i.

Bi mo ṣe n feyinti si Daura, nipinlẹ Katsina, inu mi dun pe a ti bere igba ọtun ni orilẹ-ede Nàìjíríà nipa gbigbe awon igbese to se koko ni ibẹrẹ ati pe o da mi loju pe isejọba to ñ bọ yóò mu irinajo yii lọ kunkundun lati ní Naijiria ti ọ wùmí, lati jẹ orilẹ-ede nla nih kókó.

O da mi loju pe mò ń kuro ni ọfiisi pẹlu igbagbọ pe orilẹ-ede Nàìjíríà dara ni ọdun 2023 ju ọdun 2015 lọ.

Mo dupe lowo gbogbo yin. Ọlọ́run yóò bukun fún orilẹ-ede Nàìjíríà.

 

 

GEORGE ỌLÁYINKÁ AKÍNTỌ́LÁ.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button