Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Bauchi bẹ̀rẹ̀ tit́a ajílẹ̀ fún àsìkò òjò ọdún 2023

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 250

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Bauchi, ní ọjọ Iṣẹgun, bẹ̀rẹ̀ tit́a ajílẹ̀ fún àsìkò ọ̀gbìn 2023,ní iye owó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún Náírà fún àpò kan.

Gómìnà Bala Mohammed sọ eléyìí níbi ìfilọ́lẹ̀ Àsìkò Ọ̀gbìn 2023 ati Títa Ajílẹ̀ ní Azare, olú-ìlú ìjọba ìbílẹ̀ Katagum ,ní ìpínlẹ̀ náà.

Ó sọ pé, Wọ́n ṣe èyí láti jẹ́ kí àwọn àgbẹ̀ ní èrè oko lọ́pọ̀ yanturu nínú àsìkò òjò yìí .

Wọ́n ná Iye owó tó jọjú lórí ríra Ajílẹ̀ NPK, tí ó ju igba mọ́tò lọ,òògùn fún ìkojú àwọn ọ̀tá àgbẹ̀ àti abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àwọn ẹran ọ̀sìn.”

Gómìnà wá pàṣẹ pé kí ilé-iṣẹ́ ìjọba ti ìpínlẹ̀ tó ń mójútó ètò Ọ̀gbìn láti tọpinpin àwọn àìṣedéédé tó bá wáyé látàríi títà àti pínpín Ajílẹ̀ náà.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button