Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ń darí ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀,èyí tí ó ń wáyé ní gbòngàn ààrẹ,Villa, ní ìlú Àbújá.
Igbákejì ààrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Ọ̀ṣínbàjò, ọ̀gá àgbà fún àwọn òṣìṣẹ́ ààrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ibrahim Gambari àti ọ̀gá àgbà fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀, Dókítà Fọláshadé Yẹmí-Ẹ̀san wà lára àwọn tó wà níjòókó níbi ìpàdé náà.
Àwọn tó tún wà níbẹ̀ ni Mínísítà fún àlàyé, Lai Mohammed, Ìnáwó, Ìsúná àti iṣètò orílẹ̀-èdè, Zainab Ahmed, ìdájọ́, Abubakar Malami, àti Iná, Abubakar Aliyu.


Àwọn mìíràn ni Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin, Pauline Talllen, òfurufú, Hadi Sirika, ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ọrọ̀-ajé orí ayélujára,Ọ̀jọ̀gbọ́n Isa Pantami.
Ààrẹ Bùhárí àti ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀ ń pàdé fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí gbogbo wọn ti kópa nínú ìdìbò gómìnà ní àwọn ìpínlẹ̀ wọn.
Àlàyé lẹ́kùúnrẹ́rẹ́ nígbà míràn…………
Leave a Reply