Take a fresh look at your lifestyle.

Sultan ti ìlú Sókótó Kí àwọn Mùsùlùmí kú àmójúbà oṣù Ààwẹ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 258

Ìgbìmọ̀ tó gajù lọ ní Nàìjíríà tó ń mójútó ètò Islam, NSCIA lábẹ́ ìṣákóso ààrẹ gbogbogbòò,tí ó tún jẹ́ Sultan ti ìlú Sókótó,  Alhaji Muhammad Sa’ad  Abubakar ti ṣàjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ mùsùlùmí lápapọ̀ lórí oṣù pàtàkì ààwè  1444 A.H.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí  adarí àkóso NSCIA, Zubairu Haruna Usman-Ugwu,buwọ́lù,ìgbìmọ̀ náà gbàá ládùúrà pé kí ọlọ́run fún gbogbo mùsùlùmí lẹ́mìí àti àlàáfíà láti kópa àti lérè nínú ìjọ́sìn pàtàkì náà.

Fún ìmọ̀ràn ìgbìmọ̀ rírí oṣù lápapọ̀,  Sultan wá rọ àwọn Mùsùlùmí lápapọ̀ láti wá oṣù  Ramadan 1444 A.H. ní kíákíá lẹ́yìn tí òòrùn báti wọ̀ ní Ọjọ́ọ́rú,ọjọ́ kọkàndín-lọ́gbọ̀n,oṣù Sha’aban, ọdún1444 A.H. ,tí ó dọ́gba pẹ̀lú ọjọ́ kejìlé-lógún,oṣù kẹta,ọdún 2023.Tí wọ́n bá rí oṣù náà ní ìrọ̀lẹ́ yìí,Sultan ti ìlú Sókótó yóò kéde Ọjọ́ọ́bọ̀,ọjọ́ kẹtàlé-lógún 2023 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kínní ,oṣù Ramadan 1444 A.H. Tí wọn kò bá wá rí oṣù ní ọjọ́ náà,a jẹ́ wípé,ọjọ́ Ẹtì,ọjọ́ kẹrìnlé-lógún, oṣù kẹta ni yóò jẹ́ ọjọ́ kínní,oṣù  Ramadan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button